Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Okoye Ogochukwu tí o lọ fún iṣẹ́ àbẹ ní ilé ìwòsàn kan ni Àjàó Estate, ìpínlẹ̀ Èkó, l’Órílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), tí apanimáyọdà Naijiria nfi agídí jẹ gàba lé lórí. Obìnrin yìí wípé nígbàtí dókítà Ejim ṣiṣẹ́ abẹ fún òun láti bimọ ní ilé ìwòsàn Faith City, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé dókítà náà gbàgbé abẹ sí inú òun ti ó sì ti fa àìsàn tí òhún ná owó lé lórí.
Èyí ni igbe tí obìnrin náà ké síta, nítorí ó ti ná mílíọ̀nù mẹ́ta naira sí àìsàn nàá ní oríṣiríṣi ilé ìwòsàn látí gba ìtọ́jú àti ìwòsàn.
Yíò ṣòro fún obìnrin yí láti rí ìdájọ́ òdodo nítorí íjẹgàba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa, D.R.Y. Bẹ́ẹ̀ náà ni apanimáyọdà Nàìjíría tí tọwọ́ bọ’wé àdéhùn ikú pẹ̀lú Bill Gates tí ó jẹ́ ọ̀tá Áfríkà àti ọ̀tá Olódùmarè.
Gẹ́gẹ́bí orílẹ̀ èdè Olómìnira àti aṣèjọba ara ẹni, màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò fún òmìnira wa ti ṣe àlàyé lórí àlàkalẹ̀ ìṣèjọba wá pé ìlera ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ṣe pàtàkì nítorí náà, D.R.Y kò ní wọ àdéhùn búburú kankan pẹ̀lú àwọn ìkà àti apànìyàn, a kò sì níí fi ààyè sílẹ̀ fún ayédèrú dókítà, àmójútó yíò wà fún àwọn ilé iwosan, pàtàkì jùlọ, ètò ìlera ọ̀fẹ́ yíò wá.
Àwọn ìjọba Adelé wá tí nṣiṣẹ́ lọ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nígbàtí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí Adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́, láì pẹ́ yìí ní a ó lé àwọn ajẹgàba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí gbogbo ètò wọ̀nyí lè bẹ̀rẹ̀ síí farahàn fún ìgbádùn àwa ọmọ Aládé.