Wọ́n ní tí a bá pẹ́ lórí ìgbọ̀nsẹ̀, oríṣiríṣi eṣinṣin á máa bà lé ni.

Kí àánú, ìkẹ́ àti ìgẹ̀ Olódùmarè máa wà pẹ̀lú Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ẹni tí Olódùmarè yàn fún ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá kúrò lábẹ́ ìmúnisìn òyìnbó àti agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ìlú tí Fúlàní ń darí rẹ̀.

Ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún ni ìkéde ìtúsílẹ̀ àti òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) wáyé.

Ṣùgbọ́n ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà sì ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa láti ìgbà náà. 

Ọjọ́ kéjìla oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún ni ọjọ́ pàtàkì tó tẹ̀lé ọjọ́ Òmìnira wa, tí a ṣe ìbúra-wọlé fún olórí ìjọba adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, lórí Ilẹ̀ wa, ní ìlú Ìbàdàn. 

 Pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ méjèèjì yí, kí Olódùmarè  jẹ́ kí àbùkù tó lókìkí ó ṣẹlẹ̀ sí ajẹgàba nàìjíríà láìpẹ́, fún jíjẹgàba tí wọ́n ṣì ń jẹgàba lórí ilẹ̀ wa títí di ìsiìyí.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates.

Kí ara kó ni ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, kí wọ́n sá kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) láìpẹ́, láìjìnà!

 Ìròyìn kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára sọ pé àwọn ọmọ Íbò ń ṣe òwò ọmọ-bíbí-fún-títà lábẹ́ àkóso obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Florence Ogbonna.

Bẹ́ẹ̀ ni a rí ẹnìkan tó pe ara rẹ̀ ní Abimbọla Oyeyẹmi, Agbódegbà ọlọ́pàá agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní Orílè-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá tí Dapọ Abiọdun ti ń jẹ́ gàba.

À bẹ́ ò rí nkan, ọlọ́pàá aríremáṣe nàìjíríà lórí ilẹ̀ D.R.Y ni ó gbé ẹnu òkè mọ́ ti ìsàlẹ̀, tó rò pé ọ̀rọ̀ gidi ni òun nsọ pẹ̀lú òyìnbó òfò tó ń sọ lẹ́nu.

Àwọn oríṣiríṣi eṣinṣin ọ̀hún nìyí tí wọ́n bà lé ọmọ Yorùbá, ṣùgbọ́n tí Màmá wa fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a máa jó, a máa yọ̀, torí a máa rẹ́yìn wọn! 

Ìwọ Abímbọ́lá Oyèyẹmí, tìẹ ti bá ọ, kí o mọ̀ pé ìwọ àti ìdílé rẹ tí dáràn ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí o dúró pẹ̀lú apanilẹ́kún jayé nàìjíríà, o bá wọn pawọ́pọ̀ láti jẹgàba lórí orílẹ̀-èdè Aṣèjọba-ara-ẹni, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ilẹ̀ Yorùbá ti mú gbogbo yín.