Arábìnrin kan tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí ó ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀húnúhàn ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní ó ti pariwo síta báyìí o, wípé, ìyà ti pọ̀jù ní orílẹ̀ èdè àwọn, ilé ìwé ìjọba tí ó yẹ kí ọ́ jẹ́ ọ̀fẹ́, kìí se ọ̀fẹ́ rárá, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà ní wọ́n ń gbà ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba tí ọmọ òun ń lọ, àti ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà fún aṣọ ilé ìwé.
Arábìnrin náà sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wípé, “mò ń ta omi inú ọ̀rá yí láti lè fi tọ́jú àwọn ọmọ ni kí èmi náà sì leè rí ọwọ́ mú lọ sí ẹnu, ọmọ mi pàápàá náà ń kiri omi pẹ̀lú, ní ìgbà mìíràn ṣe ni màá pa ebi mọ́ra, láti lè fi ìwọ̀ǹba owó omi tí mo bá tà ra oúnjẹ fún àwọn ọmọ mi, ìyà yí ti pọ̀jù, mi ò leè mu mọ́ra mọ́.”
Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Mo lọ sí ilé ìwé tí wọ́n ti ńkọ́ nípa iṣẹ́ olùkọ́, mo ti fi ìgbà kan ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Yẹmi Ọsinbajo kan tí ó wà ní Àjáh ní ìpínlẹ̀ Èkó, ṣùgbọ́n ní kété tí Yẹmi Ọsinbajo wọlé gégébí ìgbàkejì ààrẹ́ ni arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ngozi dá gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwé náà dúró, tí ó sì kó àwọn ènìyàn tirẹ̀ síbẹ̀, láti ìgbà náà ni mo ti di aláìníṣẹ́, tí wọn kò sì fún mi ní owó ìfẹ̀yìntì mi láti igba náà.
Ẹ bámi bẹ Yẹmi Ọsinbajo kí ó fún mi ní owó ìfẹ̀yìntì mi ò.”
Nítorí fífi ipá jẹgàba àwọn ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà yìí lórí orílẹ̀-èdè wa Democratic Republic of the Yorùbá ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn kàn wa, ṣùgbọ́n ní kété tí a bá ti lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa, gbogbo àrùn wọn kò ní dé ọ̀dọ̀ wa mọ́ nítorí ètò tiwa kò lè jọ tiwọn rárá, àwọn olórí ìjọba ti wa kò lè rí àyè ṣe ibajẹ, òfin wa yíò lòdì sí irú ìwà pálapàla bẹ́ẹ̀.
Fún ìdí èyí, àwa ọmọ Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá ń fi àkókò yí dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa tí Olódùmarè rán sí wa láti gbà wá ní déédéé ìgbà yí, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Àbíọlá. Ẹ wo bí àwọn ìjọba ìlú aríremáse yí ṣe sọ àwọn ọ̀dọ́ wọn dà, ṣé bí à bá ṣe máa bàa lọ rèé?
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa se máa ń sọ fún wa wípé, ọ̀fẹ́ ni ilé ìwé yíò jẹ́ fún àwọn ọmọ wa títí dé ilé ẹ̀kọ́ unifásítí àkọ́kọ́, àti pé iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Yorùbá, oníkálukú ni yóò ní iṣẹ́, tí a ó sì máa gba owó ọ̀yà wa ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì. Bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ojúsàájú nínú ètò ìgbanisíṣẹ́ ní ilẹ̀ Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, kò ní sí àyè fún owó ẹ̀yin gbígbà, kò sì ní sí wípé mi ò mọ èèyàn ni mí ò fi rí iṣẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ẹni náà bá ti kún ojú òṣùwọ̀n fún irú iṣẹ́ náà kò sí ìdádúró kankan mọ́ láti rí iṣẹ́.