Ọjọ́ tí wèrè bá ti mọ́ wípé wèrè ni òun, ọjọ́ náà gan-an ni ó ti ní ìwòsàn. Ọ̀rọ̀ yí ló dá lóríi fọ́nrán ọ̀kan lára àwọn gbéwiri ní ìlú akótilétà Nàìjíríà tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ndume, tó sì ń sọ báyìí wípé, òun kò ní kí wọ́n má dá ẹjọ́ ikú fún ẹni tó bá wu’wa ìbàjẹ́, ṣùgbọ́n èyí tí òun kò faramọ́ ni kí wọ́n máa dá ẹjọ́ ikú fún ẹni tó jí mílíọ̀nù tàbí bílíọ̀nù kan, èyí tí òun faramọ́ ni wípé, ẹní tí ó bá jí mílíọ̀nù tàbí bílíọ̀nù kí wọ́n rán lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére tàbí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jí trílíọ́ọ̀nù ni kí wọ́n máa pa nítorí pé owó yẹn pọ̀ púpọ̀ ẹni náà sì ti dá ọ̀pọ̀ ènìyàn lágara.
Ó tilẹ̀ tún sọ wípé, owó tí àwọn ń jí ọ̀hún, àwọn máa ń ko pamọ́ ni, láti lè lò ó fún ìpolongo ìbò ẹlẹ́ẹ̀kejì.
Ṣé ẹ ti wá ríi kedere báyìí pé kò sí ohun rere kan tó leè ti inú ìlú aríremáse Nàìjíríà jáde, nítorí pé, gbogbo ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń wù yí, wọn kò ríi bí ohun ìtìjú tí kò sì yẹ láwùjọ ọmọ ènìyàn, ìdí nìyí tí wọn ò fi leè ronúpìwàdà.
Àbí ẹ ò ríi? Àwọn ni wọ́n sì ń tọ́ka sí ìwà ìbàjẹ́ ẹlòmíràn, ó tilẹ̀ tún sọ débi pé, àwọn ènìyàn wọn náà ní ìmọ̀ nípa àwọn olóṣèlú tó ń jí owó. Ó ní owó tí àwọn njí, àwọn fi nṣe nkan fún àwọn ará-ìlú ni.
Ǹjẹ́ ẹ ríi bí ọpọlọ àṣètáánì wọn ṣe ń ṣiṣẹ́? Ìdí nìyí tí àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y kò ṣe faramọ́ òṣèlú olówó ní ọ̀nà-kọnà. Olódùmarè dára sí àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y gidigidi.