Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí òye kò yé, ni wọ́n ti béèrè pé “kí la máa jẹ,” “kí la máà mu,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ní Orílẹ̀-Èdè wa.
Ọ̀rọ̀ yí kò rújú rárá; Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nsọọ́, láti ìgbà dé ìgbà, pé nísiìyí tí a ti polongo ìṣèjọba-ara-ẹni wa, tí a dẹ̀ ti ṣe ìbúra wọlé fún Ìjọba Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ohun tí ó túmọ̀ sí ni pé a ti ní ÀṢẸ báyi láti máa wa kùsà wà, ní ilẹ̀ Yorùbá, lábẹ́ àkóso ìjọba wa, ìjọba D.R.Y, fún ànfààní ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá.
Ìwọ ni Góòlù, lithium, bitumen, epo rọ̀bì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo rẹ̀ ti wà ní ìkáwọ́ ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá báyi, láìsí ẹni tí ó nbá wa pín nkan tí Olódùmarè fún wa. A ò tíì sọ erè oko, ẹja inú omi, àwọn ìgbó wa, ibi ìgbafẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́bí màmá wa ti ń sọ fún wa, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ni Olódùmarè túbọ̀ nfihan’ni oríṣiríṣi àlùmọ́nì tí ó wà nínú ilẹ̀ wa.
Láyé, ẹnikẹ́ni kò ní wá máa kó nkan wa mọ́: àwa ni a ni ohun tí Èdùmàrè fún wa; kò ń ṣe fún ẹlòmíran Àti má yé dẹrùn- ilé ìwòsàn, ilé-ẹ̀kọ́, títì tó dára, pẹ̀lú omi tó mọ́ gaara, kò ní ni wá lára; níbo ni a ti máa rí owó ṣe ohun wọ̀nyí? Owó wà nínú ilẹ̀ wa! ÀLÙMỌ́NÌ ló njẹ́ bẹ́ẹ̀! Ìdí nìyẹn tí Màmá tí máa nsọ pé ìṣèjọba-ara-ẹni, èyí tí ó fún wa ní àṣẹ láti ṣe àkóso gbogbo ohun tí Ọlọ́run jogún fún wa, ìyẹn gan-an ni a npè ní ÒMÌNIRA.
Ọmọ ìbílẹ̀-Yorùbá ti bọ́ sí Òmìnira báyi: Ohun kan tó kù ni kí á lé àwọn wèrè tó wà lórí ilẹ̀ wa; ìṣàkóso àlùmọ́nì ilẹ̀ wa túmọ̀ sí pé a ò lọ kọ́kọ́ gba àṣẹ níbikíbi kí á tó fọwọ́ kan ohun tó jẹ́ tiwa; láarín ara wa, ní abẹ́ àkóso ìjọba D.R.Y, ni a ti máa sọ pé ohun rere báyi la fẹ́ ṣe; àlùmọ́nì ilẹ̀ wa á dẹ̀ sọ pé a ríi sọ, torí òun wà níbẹ̀ fún wa: àgàgà, a tún wá ní Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti gbé lé Màmá wa lọ́wọ́, tí ó máa fi ọ̀nà hàn wá, bí a ṣe máa ṣé, tí gbogbo rẹ̀ á yẹ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).
Kò sí ìfòyà fún wa o! Agbára àlùmọ́nì ilẹ̀ jẹ́ ìkan gbòógì nínú nkan tí orílẹ̀-èdè fi nṣe orí-ire, Olódùmarè dẹ̀ ti ṣe ọmọ Yorùbá ní olórí-ire. Gbogbo àlùmọ́nì wọ̀nyí ni wọ́n ti wà ní inú ilẹ̀ wa láti àtètèkọ́ṣe; ohun tí ó wá jẹ́ ayọ̀ wa báyi ni pé a ti wá ní ÀṢẸ lórí ohun tó jẹ́ tiwa.
Kìí ṣe èyí nìkan; Èdùmàrè tún wá jogún ọpọlọ fún àwa ọmọ Yorùbá láti ṣe ìwádi, ṣe iṣẹ́, àti gbé iṣẹ́ lóríṣiríṣi jáde nípasẹ̀ àwọn àlùmọ́nì wọ̀nyí, fún ògo, ìdùnnú àti ayọ̀ ọmọ Yorùbá – kí á lè máa yin Ọlọ́run, títí ayé, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ.