Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ lọ nforúkọ sílẹ̀, pé ẹ fẹ́ di ohunkóhun ní ìlú aríremáṣe Nàìjíríà, ìkìlọ̀ ré fún yín o! Gbogbo ẹ̀ pátá ló ní àkọsílẹ̀! Bóyá lẹ mọ̀! Ẹ máṣe rò pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kò ní mọ̀!
Gbogbo ẹ̀ ni D.R.Y máa mọ̀, nítorí pé gbogbo ìwé-ẹ̀rí tí ó fihàn pé ẹ lọ forúkọ sílẹ̀ fún ohunkóhun ní Nàìjíríà, ni D.R.Y máa gbà lọ́wọ́ Nàìjíríà. Gbogbo ìwé tó wà lọ́wọ́ wọn ni wọ́n máa kó sílẹ̀; torí àwọn náà á fẹ́ sọ pé àwọn ti ná iye owó bái-bái; wọn ò dẹ̀ lè sọ pé àwọn ná owó bái-bái láì ṣe àfihàn inkan tí wọ́n ná’wó lé lórí! Ibi tí a ti máa rí orúkọ yín nìyẹn! Lóbátán!
Ẹ̀yin tí ẹ lọ ntò, láti gba iṣu kan, tàbí búrẹ́dì, ṣé onjẹ tó máa yó yín títí ayé nìyẹn? Wọ́n nfi yín dí èpè tí wọ́n bá nṣẹ́ fún wọn, ẹ ò fura!
Ọmọ Yorùbá, ẹ dẹ́kun almájìrí ṣíṣe! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nto ìtò àlmájirí kiri, láti ìgbà ìdìbo-òṣèlú nàìjíríà, di ìsin-ìyí, ẹ máa ríran wò, àwòrán yín wà nílẹ̀ o, fídíò yín wà nílẹ̀.
Ṣé ẹ́ẹ̀ lè mú ìyà yí mọ́ra ni? Ìgbà mélo ló kù, tí ìjọba orílẹ̀-èdè Yorùbà máa wọ’nú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, tí ẹ ò wá lè mumọ́’ra? Àlmájìrí lẹ nṣe kiri lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n nf’ìyà jẹ yín!
Láti ìsiìyí lọ, títí tí ìjọba-Adelé wa máa wọ’nú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa, ọmọ Yorùbá kankan tí ó bá tún lọ ṣe àlmájìrí, ayé oní-t’ọ̀ún ti bàjẹ́ nìyẹn o!
A gbọ́ pé Nàìjíríà tún ngbé ọ̀rọ̀ ìkọ́ṣẹ́ kan kiri (vocational training). Ọmọ Yorùbá tó bá lọ forúkọ sílẹ̀ níbẹ̀, ẹ̀ẹ́ ní ẹẹ̀ ṣe’rú ẹ̀ mọ́! Àwọn Nàìjíríà ní ti wọn, ìjọba wọn ti rọ́ràn fún nkan tí wọ́n gbé síta yẹn tí wọ́n sì npe ọmọ Yorùbá ní ilẹ̀ Yorùbá si, lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ pé Yorùba ti kúrò ní Nàìjíríà.
Ẹ̀yin tí ẹ ò kì nṣe ọmọ Yorùbá pàápàá, ṣùgbọ́n orí-ilẹ̀ Yorùbá lẹ wà, tí ẹ́ sì fi orúkọ sílẹ̀ fún ohunkóhun tí Nàìjíríà gbé wá bá yín, kí ẹ mọ̀, báyi, pé ẹ ti dáràn o!
Bẹ́ẹ̀ náà ni tí ẹ bá lọ gba ohunkóhun tí àwọn ti Nàìjíríà mú wa, tí ẹ lọ ntò, tí ẹ ngba ìgbàkugbà, ìbáàṣe onjẹ tàbí ohunkóhun tó wù kó jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn ti ọmọ Yorùbá pọ̀ ju ti ẹni tí kìí ṣe Yorùbá, ṣùgbọ́n gbogbo yín ni ẹ dáràn.