Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ti wà nínú òkùnkùn látàrí ìwà àti ìṣe àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní adarí tàbí aṣíwájú pàápàá àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.

Wọn ò jẹ́ kí a mọ púpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ wa. Wọ́n a fi ẹ̀jẹ̀ sínú tu itọ́ funfun síta, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n a máa fi dúdú pe funfun fún àwa ọmọ Aládé. Wọ́n fi ẹ̀tàn gba ẹ̀sìn àwọn babańlá wa lọ́wọ́ wa, nípasẹ̀ ète tí àwọn amúnisìn fi sí wọn lórí. 

Àwọn àti ẹbí wọn nìkan ló ń jẹ ìgbádùn àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè fi táwa lọ́rẹ tó yẹ kó wà fún gbogbo ará ìlú. Nígbà àkọ́kọ́ tí àwọn amúnisìn wá sí orílẹ̀ èdè wa, inú ìgbádùn tó pọ̀ àti ìfọkànbalẹ̀ ni wọ́n bá wa, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi imú fínlẹ̀ láti mọ àṣírí ògo, ọgbọ́n, àti agbára tí Olódùmarè fún wa, ọ̀kan lára wọn tilẹ̀ sọ wípé ọ̀nà láti lè kán eegun ẹ̀yìn wa ni nípa bíba ẹni ẹ̀mí wa jẹ́, tít’ọwọ́bọ àṣà àjogúnbá àti ètò ẹ̀kọ́ wa.

Wọ́n ní tí a bá ti ní òye wípé gbogbo ohun tó bá ti ilẹ̀ òkèèrè wá ni ó dára ju tiwa lọ, a ó sọ iyì ara wa àti àṣà àjogúnbá wa nù, nípa èyí, wọn yóò leè máa darí wa bí wọ́n ti fẹ́. 

Gbogbo èròǹgbà wọ̀nyí ni wọ́n sì músẹ̀ nípasẹ̀ àwọn aláìláàánú tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba. Lẹ́yìn tí àwọn amúnisìn yí ti ṣe ìwádìí wọ́n dáadáa, wọ́n ríi wípé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ọba yí fẹ́ràn owó àti ipò lọ́pọ̀lọpọ̀, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tí kò wúlò gba odindi ènìyàn nìyí. 

Wọ́n ta ẹrú, wọ́n ta ẹrù, gbogbo àṣírí agbára àwọn babańlá wa ni wọ́n gbé lé àwọn amúnisìn lọ́wọ́.

Ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó rán ẹni bí ọkàn Rẹ̀ sí wa ní àkókò yí, màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, àwọn ni Olódùmarè lò láti ṣí wá lójú ẹ̀mí, ṣé inú òkùnkùn biribiri ni à bá wà títí di àkókò yí.

Màmá wa MOA ló jẹ́ ká mọ̀ wípé láti ìgbà tí àwọn amúnisìn ti so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́, ní wọ́n ti gbá àwọn ọba wọlẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n síbẹ̀ kí wọ́n leè máa lò wọ́n fún iṣẹ́ ibi.

Wọ́n dojú ètò ẹ̀kọ́ wa bolẹ̀, èdè tí àwọn babańlá wa ò gbọ́ wá di dandan ní ilé ìwé, lẹ́yìn tí wọ́n sọ èdè wa di ohun ìríra létí wa. Ṣébi màmá wa MOA tí kò ní bàjẹ́ fún láéláé ló jẹ́ kí a mọ̀ wípé, ìran tó bá ti sọ èdè rẹ̀ nù,irúfẹ́ ìran bẹ́ẹ̀ yóò parun ni.

Olódùmarè ti gbà ìran Yorùbá kúrò nínú òkùnkùn, aò sì ní padà síbẹ̀ mọ́ láéláé.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates