Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wípé lórí òtítọ́ àti òdodo ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé, nítorí náà, kò ní sí ojúṣàájú nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe, pàápàá ní àkókò yíyan adarí tàbí aṣojú, yálà ní ilé iṣẹ́ tàbí nínú ètò ìṣàkóso.

Àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) nìkan ni yóò máa wà ní ipò aṣíwájú ní orílẹ̀ èdè wa. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ wípé, lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.

Fún ìdí èyí, aò ní gba àjòjì kankan láàyè láti wà ní ipò adarí, aṣojú tàbí aṣíwájú ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí àyè fún àgàbàgebè, gbígba owó ẹ̀yìn tàbí ojúṣàájú nínú ètò ipò yíyan, ẹni tí ipò náà bá tọ́ sì tó sì ní àtìlẹ́yìn àwọn ará ìlú jùlọ ni yóò jáwé olúborí, nítorí pé bákannáà ni gbogbo wa, àparò kan kò ní ga jù’kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá.