Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yoruba ní ìlànà fún ètò ẹ̀kọ́ tuntun tí yíò jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Ètò ẹ̀kọ́ tó fọkàn sí ọgbọ́n àti ìmọ̀ tó wúlò fún ayé òde òní.
Ètò yìí yàtọ̀ sí àwọn ètò àtijọ́ tí ó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi ní àgbáyé.
Gẹ́gẹ́bí ìròhìn kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára ṣe sọ, ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọ mọ̀ nípa iṣẹ́ oníṣòwò àti ìmọ̀ nípa ìṣúná owó. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé Àlàkalẹ̀ tó wà fún ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wa tún jẹ́ àrà ọ̀tọ̀.
Ní kété tí Ìjọba Adelé wa bá ti wọlé sí Oríkò Ilé-Iṣẹ́-Ìjọba ni a ti máa ma rí àwọn nkan ọ̀tọ̀ náà.
Pẹ̀lú ìtọ́ni àti àǹfààní tó yẹ, àwọn ọmọ wa á ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn nkan tí Orílẹ̀-Èdè wa fẹ́ kí wọ́n mọ̀ gan-an gan, yàtọ̀ sí àwọn àdàmọ̀dì ẹ̀kọ́ tí kò fún èèyàn ní ọjọ́ ‘wá’jú.