Ìrínisí ni ìsọni lọ̀jọ̀, bí a ti rìn ni à á ko’ni. Èyí ló d’ifá fún ìgbìyànjú àwọn Yorùbá láti tún ara ṣe, láti má rìnrìn ìdọ̀tí, kí olúwarẹ̀ lè ṣe é rí láwùjọ.
Yorùbá tí ń wọ aṣọ oríṣiríṣi kí àwọn àjòjì tàbí òyìnbó tó dé ilẹ̀ wa, bẹẹ sì ni wọn kò wo àṣà ẹnìkan bẹ̀rẹ̀ aṣọ lílò, t’okùnrin t’obìnrin.
Àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣọ wọ̀nyí ì ni o tí n bá ìgbà lọ, wọ́n sì ti fi àṣà ati ìṣe ẹ̀yà míìràn rọ́pò tiwọn. Ṣẹ̀bí àwọn ní wọ́n wípé; odò kì í sàn kó gbàgbé orìsun ni?
Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà àgbáyé mìíràn, àwọn Yorùbá máa ń fi aṣọ ṣe ẹ̀ṣọ́ ara àti láti dáàbò bo ara l’ọ́wọ́ èyíkéyìí irúfẹ́ ewu àyíká.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Àmọ́ aṣọ ní ilẹ̀ káàrọ̀ òjííré jẹ́ ohun dídárà, tí ó ṣì jẹ̀ẹ́ kí àwọn Yorùbá yàtọ̀ sí àwọn àṣà tó kù ní àyíká wọn. Ìgbàgbọ́ wọn ní pé aṣọ wíwọ̀ ṣe àfihàn irúfẹ́ ẹni àti irú ipò tí ènìyàn ń ṣe láwùjọ, àti wípé oríṣii ìjáde ló ní aṣọ tí ẹ̀. Yorùbá fi ìyì púpọ̀ sí àṣà wíwọ aṣọ.
Yorùbá ti ń fi irun hun aṣọ kó tó di wípé àwọn òyìnbó dé, èyí mú kí oríṣiríṣi ohun aṣọ tó yàtọ̀ sí èyí tí àwọn baba ńlá wa fi ń ṣ’ẹ̀dá aṣọ wọ orílẹ̀-èdè wá, àmọ́ aṣọ-òkè ni gbòógì wọn ti jẹyọ. Àlàárì, sányán àti ẹtù jẹ́ oríṣiríṣi aṣọ-òkè pẹ̀lú àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Òfì, àrán, àdìre, àǹkará, léèsì, jàkáádì, alágbàá, gínnì ati dàmáàskì jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ohun èlò aṣọ tó bá ìgbà dé, tí àwọn Yorùbá ń lò láti dá aṣọ.
A le pín àwọn aṣọ yìí sí ìbámu àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n bò. Fún orí – fìlà wà fún àwọn ọkùnrin, tí àwọn obìnrin ṣì ń wọ gèlè fún-ún.
Ẹ̀wù ni orúkọ àpapọ̀ tí a fún aṣọ tí ẹyà Yorùbá ń lò láti bo apá òkè ara, láti ọrùn sí ìsàlẹ̀ dé déédé orúnkún. Aṣọ tí wọ́n fi ń bo ìsàlẹ̀ lati ìbàdí ni ṣòkòtò fún ọkùnrin àti ìró fún àwọn obìnrin.
Ní ṣókí, àwọn ọkùnrin ní oríṣiríṣi aṣọ tí wọ́n lè wọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn obìnrin náà ni aṣọ tiwọn.
Aṣọ ìbílẹ̀ àwọn obìnrin láti ayé b’áyé ni ìró, bùbá, gèlè, pẹ̀lú ìborùn àbí ìpèlé nígbàmi. Àkànpọ̀ yìí jẹ́ èyí tó ń pàṣẹ ìbọ̀wọ̀ fúnni láàrin àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin láwùjọ.
Àṣà ọkùnrin ni láti wọ ẹwù àwọ̀tẹ́lẹ̀ bíi bùbá, kafutáànì, dànsíkí, ẹsikí ati sapara sí abẹ́ àwọn ẹwù àwọ̀sókè ńlá.
Gbogbo aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí ni wọn le wọ̀ sí abẹ́ àwọn aṣọ bìí agbádá, gbárìyẹ̀, dàńdóógó, ọ̀yàlà àti súlíà; àwọn aṣọ yìí la mọ̀ sí ẹ̀wù àwọ̀sókè,díẹ̀ lára àwọn fìlà ti ọkùnrin náà ni, abetí- ajá, ìkọ̀rì, gọ̀bì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nítorí náà, ẹyín ọmọ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a padà sí orísun wa, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè rán sí wa ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí láti gbà wá kúrò l’óko ẹrú ṣe máa ń sọ fún wa wípé aṣọ ìbílẹ̀ Yorùbá wa ní a ó máa wọ̀ ní ibikíbi tí àwa ọmọ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá ń lọ, kódà ní ibi iṣẹ́ ìjọba tàbí ti aládàáni, àpẹẹrẹ èyí sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ olórí adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, ẹ wo bí bàbá wa ṣe dúró déédéé nínú aṣọ agbádá wọn tí wọ́n sì dùn-ún wò. Kò sí àṣà náà ní àgbáyé yìí tí ó dára tó àṣà àwa ìran Yorùbá, ẹ wo bí àwọn ọmọ aládé ṣe ńwọ àwọn aṣọ tí kò bu’yì kúnni láwùjọ lónìí tí a sì f’ọwọ́ rọ́ àṣà ìw’ọṣọ wa sí apá kan, tí ẹlòmíràn bá wọ aṣọ náà tán, kò ní leè gbé apá tàbí gbé ẹsẹ̀, ṣé bí a ṣe bàa lọ́wọ́ àwọn babańlá wa nìyẹn ni?
Nínú ìsèjọba wa tuntun tí a ti bẹ̀rẹ̀ yìí, gbogbo àwọn àṣà wa wọ̀nyí ni a ó padà sí nítorí wípé, àṣà Yorùbá dùn púpọ̀.