Ajá Tó Máa Sọnù Kì Í Gbọ́ Fèrè Ọlọ́dẹ
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XÀwọn olùgbé àwùjọ Bámgbádé ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọbáfẹ́mi Owódé tí ó’ wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, tí ké gbàjarè síta sí ìjọba tí ńfagídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ògùn pé omi tí àwọn ńlò kò dára rárá, wọ́n ṣe àpèjúwe omi wọn náà gégẹ́bí omi ẹrọ̀fọ̀ tí ó sì léwu.
Wọ́n fi ẹ̀dùn ọkàn ṣàlàyé pé omíi náà ńṣokùnfà oríṣiríṣi àìsàn bíi àrùn onígbáméjì, àwọn oríṣiríṣi àrùn kúrúnà, pàápàá jùlọ ní ara àwọn ọmọdé.
Wọ́n tún wá tẹnumọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni omi náà ti rán lọ sí ọ̀run láì rò tẹ́lẹ̀. Wọ́n wá ńbéèrè fún omi tí ó dára lọ́wọ́ ìjọba ajẹgàba ìpínlẹ̀ Ògùn.
Ara ẹ̀tọ́ aráàlú ni omi tó dára fún mímu, wíwẹ̀ àti lílò fún ohun gbogbo láì sí ewu kankan, ṣùgbọ́n àwọn ìjọba ajẹgàba Nàìjíríà kò ṣetán láti fún ẹnikẹ́ni ní ẹ̀tọ́, ikú ní wọ́n ńgbèrò fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ìdí reé tí wọ́n ṣe kọ̀ láti kúrò ní orílẹ̀-èdè wa, tí wọ́n ńtẹ̀síwájú láti máa fi agídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa pẹlú ìṣekúpani àti olè jíjà.
Wọ́n sì mọ dájú pé ilẹ̀ Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ àti pé a ti di orílẹ̀-èdè olómìnira tí ó ní ìjọba tirẹ̀, síbẹ̀, wọ́n ńtẹ̀síwájú láti máa hùwà ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àgbáyé.
Ṣùgbọ́n o, alátiṣe wa ló níláti mọ àti ṣe ara rẹ̀, ó di dandan báyìí kí àwa ọmọ Democratic Republic of the Yorùbá dìde láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa láti gba ètọ́ wa kí a lè máa gbádùn àwọn ohun amáyédẹrùn tí orílẹ̀-èdè Yorùbá ní fún wa.
Ní orílẹ̀-èdè Yorùbá, àwọn ìjọba wa yíò ṣètò omi ẹ̀rọ tó mọ́ gaara, tí yíò sì wọlé kọ̀ọ̀kan fún mímu àti lílò, kò sí ẹnikẹ́ni tí yíò máa lọ pọn omi odò tàbí kànga rárá, èyí yíò tún ṣe ìrànlọ́wọ́ láti kọjú ìjà sí gbogbo ààrùn tí omi lè fà.
Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ló ní àwọn odò tí a ti lè fa omi tí a ó ṣe àtúnṣe rẹ̀ ní ọ̀nà ìgbàlódé tí yíò sì wúlò ní ọ̀nà gbogbo nígbàtí ìjọba wa bá ti fàá wọnú ilé kọ̀kan. Inú ìgbádùn la bọ́sí yẹn.