Ọkùnrin òyìnbó kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Jim Breuer, ni a ti rí nínú fọ́nrán kan tí ó sọ pé ìwà ibi pọ̀ nínú ayé yí – àfi ìgbà tó mẹ́nu lé àwọn oníṣẹ́ ibi náà: ó ní, wọn ò kì nṣe èèyàn, ó ní ẹni ibi gbáà ni wọ́n, ó tọ́ka wọn gẹ́gẹ́bí àwọn olórí agbègbè, àwọn gómìnà, tí ó jẹ́ pé wọ́n njẹgàba lórí ará ìlú, tí wọ́n nhùwà agbésùnmọ̀mí, tí wọ́n nmú kí ìdílé ó dàrú, kí àwọn ènìyàn ó pàdánù iṣẹ́ wọn, tí wọ́n tún nfi orí ẹnìkan gbá ti ẹnikèjì. Ó ní àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ngba owó-orí tí wọ́n dẹ̀ nfi ṣe bí ó bá ti wù wọ́n!
O ní, nínú ilé òun pàápàá, òun ri pé wọ́n ti kọ́ àwọn ọmọ òun ní ẹ̀kọ́-kẹ́kọ láti ibi tí wọ́n tí lọ kẹ́kọ, àwọn ọmọ náà kò ní ọ̀rọ̀ ọmọlúàbí lẹ́nu, bí wọ́n bá tilẹ̀ nbá òun sọ̀rọ̀.
Ó sọ pé, ìgbógun-ti-‘ni ni eléyi jẹ́, láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó pera wọn ní ìjọba ìlú wọn. Ó ní wọ́n ti gbógun ti ọpọlọ àti ìrònú àwọn ará-ìlú, wọ́n gbógun ti ìgbésí-ayé wọn, wọ́n gbógun ti jíjẹ́-ẹni-ẹ̀mí wọn.
Ó sọ pé ó ṣe’ni láanú pé àwọn èèyàn ò gbàgbọ́ pé irúfẹ́ ìwà ibi wọ̀nyí wà, bẹ́ẹ̀ ó dẹ̀ wà, àti pé ìyàl’ẹnu ni ó jẹ́ tí àwọn èèyàn bá mọ àwọn ìkà wọ̀nyí, torí àwọn tí oò lè fọkàn sí ni!
Ṣé, àwọn aláwọ̀dúdú máa nrò pé òyìnbó ò kì nṣe ibi, bẹ́ẹ̀ kò dẹ̀ rí bẹ́ẹ̀; bí a ṣe gbọ́ ní ìgbà kan rí, àfi bí ẹni pé àwọn angẹ́lì ibi sọ̀ kalẹ̀ sí apá ọ̀dọ̀ wọn ni.
Ṣùgbọ́n tìtorí ohun mèremère tí wọ́n máa nṣe sí ìlú wọn, nígbà tí wọ́n bá ti jí nkan kó ní Áfríkà tán, a máa nrò pé kò sí ibi tí wọ́n nṣe ní ìlú tiwọn, àfi ìgbà tí irú àwọn bíi ọkùnrin Breuer yí bá sọ̀rọ̀ síta.
Ṣebí àwọn náà ni a npè ní amúnisìn àgbáyé: ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó fún Ìyá Ìran Yorùbá, màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ní oore-ọ̀fẹ́ láti gbà wá sílẹ̀, tí iṣẹ́ dẹ̀ tún ntẹ̀síwájú! Ìdí nì yí tí Màmá fi máa nsọ pé ìrìn-ẹ̀mí ni, kò sí ẹni tí ó lè fi ara rìn-ín, nítorí àwọn amúnisìn náà burú jáì! Ṣùgbọ́n, Ọmọ Yorùbá, ayọ̀ ni tiwa!
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- OLÓRÍ ÌJỌBA ADELÉ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, BÀBÁ WA, MỌBỌ́LÁJÍ ỌLÁWÁLÉ AKINỌLÁ ỌMỌ́KỌRẸ́, BÁ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ SỌ̀RỌ̀ NÍ ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ Ọ̀DỌ́
- Ọ̀RỌ̀ OLÓGO LÁTI ẸNU ÌYÁ WA, ÌRÁNṢẸ́ OLÓDÙMARÈ, ÌYÁ-ÀÀFIN MODÚPẸ́ ONÍTIRÍ-ABÍỌ́LÁ, NÍ ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ ÀWỌN Ọ̀DỌ́
- SEYI MAKINDE, Ẹ̀ṢẸ̀ RẸ̀ Ń PỌ̀ SÍ LÓJOOJÚMỌ́
- ÒṢÌṢẸ́ PA Ọ̀GÁ WỌN NÍ ÌLÚ ÀKÚRẸ.. HÀÀ!