Nàìjíríà, ètò-amúnisìn, tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè; tí kò tilẹ̀ ní àṣẹ tàbí agbára ìṣàkóso-ara-ẹni lábẹ́ òfin kankan ní àgbáyé, njẹ́ iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò rán wọn, ní orílẹ̀-èdè tí kìí ṣe ara ètò amúnisìn wọn!

Agídí-ìjẹgàba tí ó nṣe wọ́n, ló nmú wọn hu ìwà-kí’wà.

Ilẹ̀ Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti kúrò lára Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún; bẹ́ẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso-ara-ẹni  tiwa láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Nàìjíríà, ètò amúnisìn, kò ní ẹ̀tọ́ kankan tàbí ìdí kankan, rárá, láti wá máa ṣe rádaràda ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), ṣùgbọ́n, ìgbéraga, ìwà-ìjẹgàba àti ìtànjẹ “ta-ló-máa-mú-mi” òun ni ó nṣe wọ́n! Ẹ̀tẹ́ wọn níwájú àgbáyé sì ti dé tán.

Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ pé ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni ó ti ṣẹlẹ̀ – àwọn òṣìṣẹ́ ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní nàìjíríà, látì ilé-iṣẹ́ wọn tí wọ́n npè ní EFCC, àwọn ni wọ́n tàgẹ̀rẹ̀ máa jẹ́ iṣẹ́ tí D.R.Y kò rán wọn [torí D.R.Y kìí ṣe ara Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ ni a ò bẹ nàìjíríà tàbí EFCC wọn níṣẹ́ kankan!].

Àwọn òṣìṣẹ́ nàìjíríà wọ̀nyí ni a gbọ́ pé wọ́n lọ sí ibi kan ní ìpínlẹ̀ Èkó, ṣùgbọ́n ìròyìn náà kò dárúkọ ibẹ̀ pàtó. Wọ́n ní wọ́n mú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ China àti àwọn míràn bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sọ pé wọ́n nkọ́ àwọn kan ní ibi tí wọ́n ti mú wọn yí, wọ́n  nkọ́ wọn ní olè-orí-ẹ̀rọ-ayélujára èyí tí àwọn kan npè ní “yahoo,” wọ́n sì nsan owó fún wọn.

Gbogbo ìwọ̀nyẹn kò kàn wá o! A ò bẹ nàìjíríà kó bá wa mú ẹnikẹ́ni tí ó nṣe ohunkóhun ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y. Kí Nàìjíríà fúnra rẹ̀ ó kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y ni a sọ.

Agídí yín, ẹ̀yin ètò-amúnisìn tó njẹ́ nàìjíríà, tí ẹ kìí ṣe ìlú, tí ẹ kìí ṣe orílẹ̀-èdè, agídí yín nṣe àkóbá lọ́wọ́lọ́wọ́ fún yín; á tó ye yín, torí ojojúmọ́ tí ẹ ti fi dúró sí orí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni ẹ máa san.

Ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal