Ohun tí a bá ṣe lónìí, ìtàn ni yóò dà bó d’ọ̀la. Nínú ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) sọ láìpẹ́ yí, nípa àwọn ọ̀dàlẹ̀ kan tí wọ́n ń sọ ìsọkúsọ wípé, tani ó fún màmá wa MOA ní àṣẹ, àwọn jọ ní D.R.Y ni, kò lè là lé àwọn lọ́wọ, àwọn máa dàárú ni tí adelé bá ti wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́-ìṣàkóso D.R.Y:
MOA sọ fún wọn wípé, irọ́ ó, a ò jọ ni D.R.Y, àṣìṣe ńlá gbáà ni ẹ ṣe pé a jọ ni D.R.Y, gbogbo àwọn I.Y.P tó dúró lórí òtítọ́ àti òdodo ni a jọ ni D.R.Y. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ọ̀tá wọ̀nyí àti ẹ̀yin ọ̀bàyéjẹ́, a ò jọ ni D.R.Y.
Màmá wa MOA wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíi láwẹ́-láwẹ́ fún wọn, gbogbo àwọn ọ̀nà tí àwọn ọ̀dàlẹ̀ yí ti ṣe àtakò lọ́kan-ò-jọ̀kan, bí wọ́n ṣe kó ara wọn jọ pé àwọn ńṣe ìjàǹgbara láti máa tan àwọn ènìyàn láìni ètò kankan, bí wọ́n ṣe kó àwọn kan síta láti máa sọ̀rọ̀ àtakò lórí isẹ́ tí Olódùmarè rán màmá wa MOA pàápàá nígbà tí a kéde òmìnira orílẹ̀ èdè D.R.Y, àti nígbà tí a ṣe bọ́si ipò ẹ̀tọ́ rẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
MOA ní kí wọ́n lọ ṣe ìwádìí tí wọ́n bá ní ẹni tó ní ìmọ̀ dáadáa bóyá gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yí jẹ́ ọ̀ràn dídá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí pé gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti òkè dé’lẹ̀ láti tako ìgbéga ọmọ Yorùbá ni.
MOA ní ẹnu wo ni ẹ wá fẹ́ fi sọ̀rọ̀ pé a jọ ni D.R.Y. Ṣé ẹ ti gbàgbé gbogbo àtakò tí ẹ ṣe sí ọmọ Yorùbá. Àwọn ọ̀dàlẹ̀ wọ̀nyí tún ní wọn ò ní jẹ́ kí a lo àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso (blueprint) tí Olódùmarè gbé fún ìran Yorùbá, wọ́n ní àwọ́n máa ṣe òfin àti àlàkalẹ̀ tiwọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì nsọ pé wọ́n máa dàárú ni. Ẹ ti dá ọ̀ràn, ọ̀run àti ayé sì ti bínú sí gbogbo yín.
Ẹ gbà fún Ọlọ́run, ẹ gbà fún blueprint ọwọ́ MOA.