Ọ̀rọ̀ kan tí a ní láti mọ̀, kí ó yé wa, dáadáa, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ni pé – a ti kúrò ní “ìrìn-àjo”, a ti di Orílẹ̀-Èdè báyi – Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y). Ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé wa dáadáa, nítorí òfin wà, tó rọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè – èyí tí ó sì yàtọ̀, pátápátá, sí ọ̀rọ̀ “ìrìn-àjò” tàbí “ìjà-n-gbara.”

Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ni wọ́n sọ nkan-kan ní àìpẹ́ yí, tí ó tún rán wa léti nípa èyí. 

Màmá wa MOA gbé ohùn síta, pẹ̀lú àṣẹ, wọ́n ní, gbogbo ẹni tí ó bá ngbé ohùn sí afẹ́fẹ́; gbogbo ẹni tí wọ́n ní ìkànnì kan tàbí òmíràn, ìbáàṣé ní fífi ohùn síta tàbí ránṣẹ́ ni, tàbí ní títẹ-nkan ránṣẹ́, tí a fi nbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, tí o sì ti fi ẹnu ara rẹ sọ pé “Yorùbá” tàbí ọ̀rọ̀ lórí “Yorùbá” ni ìkànnì òhun wà fún – (ẹnu ara rẹ ló fi sọ́, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ipá mú ẹ), Màmá wa MOA sọ pé kí gbogbo ẹni bẹ́ẹ̀ lọ yí ìrònú wọn padà o! kí wọ́n mọ̀ pé a ò sí nínú “ìrìn-àjò” tàbí “ìjà-n-gbara” mọ́.

A ti di ORÍLẸ̀-ÈDÈ (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), báyi. Nítorí náà, kí gbogbo ẹni bẹ́ẹ̀, ní gbogbo ìkànnì bẹ́ẹ̀, tí wọ́n fún’ra wọn sọ pé ọ̀rọ̀ Yorùbá ni ìkànnì náà wà fún, kí wọ́n ri pé, nígbà gbogbo àti nínú ohun gbogbo tí wọ́n bá nṣe lórí ìkànnì náà, kí wọ́n bu ọ̀wọ̀ fún orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni D.R.Y. 

Nítorí èyí, ẹ máṣe ṣe ohunkóhun tàbí sọ ohunkóhun ní orí ìkànnì ọ̀ún, tí ó lòdì sí, tàbí tako orílẹ̀ èdè aṣàkóso-ara-ẹni D.R.Y. 

MOA ní kí ẹ ṣe àyípadà nkan tí ẹ ngbé jáde, àti ọ̀nà tí ẹ fi ngbe jàde! Kí ẹ jẹ́ kí nkan tí ẹ bá ngbé jáde, báyi, kí ó jẹ́ fún Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

Gbogbo ohun tí ẹ bá nṣe, kí ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ fún D.R.Y. Màmá ní, YORUBA FIRST ni o! Kí gbogbo nkan tí ẹ bá nṣe lórí ìkànnì náà, kó jẹ́ fún I.Y.P ti D.R.Y. Kí ó jẹ́ fún ìgbéga D.R.Y, ìgbélárugẹ D.R.Y, nítorí pé, níbi tí a dé báyi, kí ó yé wa dáadáa, ó ti di ORÍLẸ̀-ÈDÈ.

Màmá wa MOA sọ pé nkan-kí’nkan tí ẹ bá fẹ́ ṣe, ìrúfẹ́ ètò ìyóòwù tí ẹ bá nṣe, tí ẹ bá ti fi ẹnu ba “YORÙBÁ,” lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí ẹ máa fi “D.R.Y” si, pé, orílẹ̀-èdè ni! – Ẹ bọ̀wọ̀ fún ìṣàkóso-ara-ẹni D.R.Y.

Ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe I.Y.P, tàbí ará-ìlù (citizen D.R.Y) tàbí ẹni tí ó ngbé ní D.R.Y, tí kò bá bọ̀wọ̀ fún pé orílẹ̀-èdè ni D.R.Y, àti pé orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni ló jẹ́, MOA sọ pé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, áá tẹ́ gidi gan-an ni. 

Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbé ohunkóhun kalẹ̀, tí o sì sọ pé fún “Yorùbá” ni ó wà fún, pé, fún “I.Y.P” ni, jọ̀wọ́, fi “D.R.Y” si, kí o sì ríi pé, nkan tí o ngbé jáde, àti ọ̀nà tí o fi ngbe jáde, ti “D.R.Y” ni; ti “YORUBA FIRST” ni, fún ọmọ Yorùbá ni.

Tí ọ̀rọ̀ D.R.Y kò bá kàn ẹ́, yí nkan tí o ngbé síta lórí ìkànnì rẹ, yi sí nkan-kí-nkan tí o bá fẹ́; ṣùgbọ́n má ṣe àṣìṣe sọ pé Yorùbá ni nkan tí o nṣe wà fún kí o sì máa sọ ìsọkúsọ lẹ́nu. Má dan-wò!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal