Kí Olódùmarè, nínú Àánú Rẹ̀, kí ó gba adúláwọ̀ kúrò nínú ìrònú-ẹrú àti ìmúnisìn; ní ti àwa ọmọ Ìbílẹ̀-Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), a ti rí Àánú gbà; Olódùmarè ti rán Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) sí wa láti là wá lójú. 

Àwa ti mọ̀ pé olè ni amúnisìn. Wọ́n wá láti jí, láti pa, àti láti parun! Láti ìgbà-dé-ìgbà, tí Màmá wa MOA bá ti nbá wa sọ̀rọ̀, ni wọ́n máa nfi àwọn nkan wọ̀nyí yé wa. 

Ẹ jẹ́ kí á ṣe ìrántí ohun tí ìkan nínú àwọn amúnisìn sọ, ní òjì-lé-l’ẹgbẹ̀sán-ọdún ó dín márun, ní ọjọ́ kéjì oṣù èrèlé. Ó sọ fún àwọn Gẹ̀ẹ́sì ẹgbẹ́ rẹ̀, wípé, ọrọ̀ tí òun ti rí ní Áfríkà, òun kò rí irú rẹ̀ rí ní ibikíbi. Èyí túmọ̀ sí pé, kò sí irú ọrọ̀ bẹ́ẹ̀ ní ìlú tiwọn, Ìlú-Òyìnbó.

Gbogbo ìwà-ìgbéraga tí àwọn òyìnbó nhù nísiìyí, irọ́ ló dúró lé lórí! Gbogbo ohun tí àwọn òyìnbó fi ṣe ọrọ̀ lóni, ilẹ̀ aláwọ̀dúdú ni wọ́n ti ji! Ṣé a rántí pé, wọ́n jí oríṣiríṣi nkan ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n jí Ilẹ̀kùn, wọ́n tún jí àga pàápàá.

Kí a máṣe tẹríba mọ́, láyé, fún òyìnbó kankan, ọmọ Yorùbá! Olè paraku ni amúnisìn! Ohun tí wọ́n jí, tí wọ́n ṣì nrí-jí, káàkiri Áfríkà, òun ni wọ́n fi nṣe ọrọ̀ tí wọ́n sì fi njẹgàba lé àwọn aláwọ̀dúdú ní oríṣiríṣi ọ̀nà ní àgbáyé! Ṣùgbọ́n ní tiwa, Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), a ti bọ́. Ṣùgbọ́n a sì tún máa tẹ̀síwájú láti mú gbogbo ohun tí ó bá jọ mọ́ ìrònú-ìmúnisìn, pátá, kúrò nínú ọpọlọ wa!

Fọ́nrán kan ni a rí, ní àìpẹ́ yí, lórí ẹ̀rọ ayélujára. Fọ́nrán yí fi hàn, gbangba, bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún oríṣiríṣi iṣẹ́-ọwọ́, iṣẹ́-ọnà, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ, tí àwọn amúnisìn wọ̀nyí jí kúrò ní Áfríkà, bí ó ṣe wà káàkiri ìlú òyìnbó lóni, tí wọ́n tún nfi ìgbéraga sọ pé àwọn ò lè fií sílẹ̀ nítorí pé, gẹ́gẹ́bí wọ́n ti sọ, wọ́n ní ó wà ní ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn, ju ọ̀dọ̀ àwa oní-nkan lọ! Àbí ẹ ò rí ọ̀rọ̀-ẹ̀gbin, ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí láti ẹnu òyìnbó-amúnisìn sí aláwọ̀dúdú?

A ò gbọ́dọ̀ ṣàì má fi iyè si pé, ohun ìní-wa, ohun-àjogúnbá wa, lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ó wà lọ́wọ́ àwọn òyìnbó-amúnisìn, kò sì gbọ́dọ̀ gbé sí’bẹ̀.

Ọkùnrin tí ó sọ ọ̀rọ̀ nínú fọ́nrán tí a rí náà, sọ pé, ní ìlú London ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti ìlú Paris ní ilẹ̀ àwọn Faransé, nṣe ni àwọn ilé-ìfi-ohun-ìyebíye-pamọ́-sí, kún fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ohun ẹ̀dá-ọwọ́, idẹ, àgbélẹ̀rọ-ènìyàn àti oríṣiríṣi ẹ̀dá-ọwọ́-fún-ìbòjú, láti ilẹ̀ Áfríkà, kún ìlú òyìnbó wọ̀nyí ní rẹpẹtẹ!

Ọkùnrin yí sọ pé gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, ní ẹyọ-kọ̀ọ̀kan wọn, ni wọ́n sì kọọ́ si lára pé kò sí iye tó pọ̀, láyé, tó le rà-á! Ó wọ́n ju ohun tí owó lè rà lọ!

Ọkùnrin yí wá la’hùn! Ó ní gbogbo nkan tí ó kọjá ìdíye-lé-lórí wọ̀nyí, nṣe ni àwọn òyìnbó jí wọn wá láti Áfríkà.

Ẹni tí ìrònú ẹ̀ bá máa rí ìgbàlà kúrò nínú èrò-oko-ẹrú-ìmúnisìn, kí ó yára gbọ́: òyìnbó-amúnisìn jalè Áfríkà, ẹ̀rí sì wà fún èyí! Àwọn fún’ra wọn ni wọ́n gbé ẹ̀rí síta – ó wà káàkiri ibi tí wọ́n kó wòn sí, káàkiri ìlú òyìnbó wọn. 

Ọkùnrin yí sọ pé, ní àkókò tí àwọn-òyìnbó-amúnisìn wọ̀nyí jóko sí Áfríkà tí wọ́n njẹgàba, nṣe ní wọ́n kó ẹrù Áfríkà.

Ọkùnrin náà sọ pé lára àwọn ibi tí wọ́n ti jí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan, ni àwọn Ìṣàkóso Bìní, Ìṣàkóso Mali, àti Ìṣàkóso Congo.

Tí a bá rántí, dáradára, Màmá wa, MOA, ti fi yé wa pé, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Ìṣàkóso Ọ̀yọ́, ṣùgbọ́n, nìtorí bí Yorùbá ṣe wà lókèlókè tó, àwọn òyìnbó wọ̀nyí, wọn ò fẹ́ kí àwọn ènìyàn ó mọ gíga àti títóbi-ògo ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n nmọ̀-ọ́-mọ̀ má sọ̀rọ̀ ìṣàkóso-Ọ̀yọ́ àtijọ́ (Old Oyo Empire), kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa ru ìṣàkóso Bìní sókè; ṣé ó yé wa? Àwa mọ̀ pé, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn nkan tí òyìnbó-amúnisìn kó ní ilẹ̀ Áfríkà, ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti ko!

Nígbàtí àwọn OLÈ aláwọ̀-funfun wọ̀nyí ò bá rí nkan sọ mọ́, wọ́n á ní gbogbo àgbáyé ló ni àwọn ẹrù wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ohun-àdáyéba!

Ṣùgbọ́n o, ẹ jẹ́ kí á ṣì máa ba bọ̀ ná, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, ẹ jẹ́ kí á máa ṣe ìgbáradì fún Àjọyọ̀ wa káàkiri Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ẹni tí a ńwò kì í wò’ran