Àgbà kìí wà lọ́jà k’órí ọmọ tuntun ó wọ́, bí àwọn babańlá wa ṣe máa ń sọ nìyí. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, àwọn àgbà tó kù s’ọ́jà gan-an orí ti kúrò ní ọrùn wọn ó ti wà ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀.
Ní ìgbà láéláé tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan bá ṣẹlẹ̀ láàárín ìlú, wọ́n á ní kí a fi tó àwọn àgbààgbà ìlú létí, pàápàá jù lọ àwọn ọba láti lè yanjú ọ̀rọ̀ náà ní pẹ̀lẹ́-pùtù àti láti ríi dájú pé kò sí wàhálà láàárín ìlú.
Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ lónìí, nítorí pé ẹni a gbójú okùn lé ò j’ẹni agba. Ṣébi àwọn àgbààgbà tí a ń sọ yí ló wá ń gbà’bọ̀dè fún ìran Yorùbá lónìí tí àwọn amúnisìn ńlò láti da ilẹ̀ Yorùbá rú àti láti ba ayé àwọn ọ̀dọ́ jẹ́.
Tí wọ́n bá ṣáà ti fún wọn ní owó péréte tí wọ́n sì fi wọn sórí ipò tí wọn ò tọ́ sí, kódà bí ẹní kí wọ́n gé orí gbogbo ìlú kan wá, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni tó bá ṣáà ti la ti owó lọ àti ipò.
Àwọn amúnisìn náà sì ti mọ àṣírí yí, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ wí pé, tí wọ́n bá ti fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ aburú kan ní ilẹ̀ Áfríkà pàápàá ní ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba àti àwọn bọ̀rọ̀kìnní ìlú ni wọ́n máa ń gbà wọlé, nítorí wọ́n mọ̀ wípé ohun tí wọ́n bá ti sọ ni àwọn ará ìlú yóò ṣe. Àwọn ni ọ̀tá inú ilé, àwọn ló kó àwa ìran Yorùbá sínú ìgbèkùn amúnisìn, ṣé tí kò bá sí olè ilé, olè ìta kò lè rí àyè láéláé.
Ṣùgbọ́n òpin ti wá dé bá gbogbo rẹ̀ báyìí, nítorí pé ojú wa ti là nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti là wá lójú, tí wọ́n ṣí iyè wa sí oríṣiríṣi àwọn ohun tó farasin.
Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti dúró. Ìran Yorùbá ti bọ́ lọ́wọ́ amúnisìn. Kò sí ọba mọ́ láti ìgbà tí àwọn àmúnisìn ti yọ ọwọ́ wọn kúrò láwo, bẹ́ẹ̀ ni kò sí bọ̀rọ̀kìnní mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, gbogbo àwa ọmọ Yorùbá ni a ní adé lórí. Nítorí náà, òpin ti dé bá iṣẹ́ àwọn ọ̀tá inú ilé wọ̀nyí.
Ọpẹ́lọpẹ́ màmá wa MOA tí wọ́n jẹ́ kí a mọ̀ wípé Orílẹ̀ èdè tí wọ́n bá ti jẹ́ Orílẹ̀ èdè Olómìnira, kìí sí ọba ní irúfẹ́ Orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀. Ṣé àwa ò kúkú mọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn ọ̀tá inú ilé yí ti ń fi ìyà jẹ ìran Yorùbá. A ò mọ̀ pé wọ́n kàn fi wọ́n síbẹ̀ láti máa lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ àwọn amúnisìn ni.
Bí ọmọ wẹ́wẹ́ ṣe ń kú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́ ń pokùnso ní ojú ayé wọn, síbẹ̀, wọn ò rí bí ohun èèwọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà tí kò sí ìfẹ́ àwọn ará ìlú ní ọkàn wọn.
Àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní bọ̀rọ̀kìnní ìlú náà tó yẹ kí wọ́n jẹ́ agbẹnusọ àwọn mẹ̀kúnnù, àmọ̀rí ìbáà kú ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ àwa ọmọ Aládé ṣe. Wọn ò tilẹ̀ fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó gbé’rí kó má baà yẹ̀wọ́n lọ́wọ́ wò, àwọn náà mọ̀ wípé tí ọwọ́ ẹni bá ti tẹ èkú idà, a ó béèrè ikú tó pa baba ẹni.
Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti tà fún àjèjì tán, nítorí àwọn ló ní owó gọbọi láti ra dúkìá káàkiri, bí wọ́n bá fẹ́ ta ilé tàbí ilẹ̀, wọn ò jẹ́ tàá fún ọmọ Yorùbá, ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n tàá fún àjèjì tí wọn ò mọ ẹyẹ tó ṣuú.
Bí ẹ sọ èdè Yorùbá sí irú wọn, wọ́n á fa ìbínú yọ, nítorí wọ́n ti ka èdè babańlá wọn sí èdè tí kò ṣeé gbọ́ s’étí, àbí ẹ ò ri pé òpònú lásán-làsàn ni àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní bọ̀rọ̀kìnní wọ̀nyí. Báwo ni èdè babańlá ẹni ṣe ń di ohun ìríra létí ẹni? Ẹ̀bi wọn sì kọ́, ipò àti owó tí àwọn amúnisìn ń fún wọn ló sún ọpọlọ wọn sẹ́yìn.
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá ìran Yorùbá wípé àwa ọmọ Aládé ti bọ́ lọ́wọ́ amúnisìn, kí ẹ tún gbọ́ lẹ́ẹ̀kan síi, kò sí èdè ẹrú mọ́ ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, èdè Yorùbá pọ́ńbélé ni a óò máa sọ níbi gbogbo. Ẹni tí kò bá tẹ́lọ́rùn kó kọjá lọ sí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, níbẹ̀ ni wọ́n ti k’ẹ́ran m’érò tí wọ́n so irun ‘wájú pọ̀ mọ́ t’ìpàkọ́.
Kò sí ọba mọ́, kò sí ìjòyè bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí bọ̀rọ̀kìnní mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá, gbogbo wa ni adé wà lórí wa. Oníkálukú ní yóò ní iṣẹ́ lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́. Olówó àti Ọlọ́rọ̀ ni gbogbo wa, àparò kan kò sì ní ga jù ‘kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá, bákannáà ni gbogbo wa.