Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítiri-Abíọ́lá, ti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn gómìnà ìlú-agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọ́n njẹgàba sorí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), orílẹ̀-èdè wa, pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi o, kí wọ́n jọ̀wọ́ iṣẹ́ sílẹ̀ fún àwọn alákoso (DG) ètò-ìṣúná (finance) àti Adájọ́-Àgbà ní gbogbo ìpínlẹ̀ wa (D.R.Y) tí wọ́n gàba lé lórí.
Èyí ni Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn (nìbi tí Ṣèyí Mákindé ti jẹgàba, tí ó njẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀); Ìpínlẹ̀ Èkó (níbi tí Jídé Sanwó-Olú ti nhùwà agbésùnmọ̀mí); Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun (níbi tí Adémọ́lá Adélékè tí jẹ́ aṣojú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíría tí ó fi ipá dúró sórí ilẹ̀ D.R.Y), Ìpínlẹ̀ Ògùn (èyí tí Dàpọ̀ Abíọ́dún ti njẹgàba); Ìpínlẹ̀ Èkìtì (èyí tí Oyèbánjí ti nṣiṣẹ́ ẹrú-ikú fún nàìjíríà tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè); Ìpínlẹ̀ Ondó (èyí tí Ayédatiwa ti ntan ara rẹ̀ jẹ pé òun nṣe gómìnà); Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ ti Àtijọ́ (níbi tí Abdulrahman Abdulrazaq ti njẹgàba níbi tí wọ́n pè ní Kwara, àti Ododo bákan-náà tí ó njẹgàba ní apákan ibi tí wọ́n pè ní Kogí).
Àwọn agbésùnmọ̀mí mẹ́jọ yí ní Màmá wa fi ohùn ránṣẹ́ sí o. Màmá ṣe àlàyé kíkún lórí bí Nàìjíríà kìí tií ṣe orílẹ̀-èdè rárá-rárá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ Ètò Amúnisìn Ìlú Gẹ̀ẹ́sì, tí ètò náà tilẹ̀ ti parí ní ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlá; bẹ́ẹ̀ ni Màmá ti kọ ÀKỌSÍLẸ̀ ìwé sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìlú àti orílẹ̀-èdè gbogbo káàkiri àgbáyé, ní èyí tí wọ́n tú àṣírí yí, tí wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn olórí ìlú (ààrẹ) wọ̀nyí, ní àkótán, pé, kí wọ́n kàn sí ìjọba Ìlú Gẹ̀ẹ́sì, pé, lọ́wọ́lọ́wọ́, kí wọ́n ri pé kò sí àyè fún rúkèrúdò àti ogun èyí tí ìjọba ètò-ìmúnisìn tí Ìṣèjọba Gẹ̀ẹ́sì gbé kalẹ̀, tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, npète rẹ̀, àti pé Ìtàgẹ̀rẹ̀ sí, àti Ìjẹgàba àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà àti àwọn gómìnà Nàìjíríà wọ̀nyí, lórí Ilẹ̀ Ìṣèjọba-Ara-Ẹni ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ níláti d’opin BÁYI!
Lẹ́yìn èyí ni Màmá wá fi ohùn ránṣẹ́ sí àwọn agbésùnmọ̀mí mẹ́jọ tí wọ́n pe ara wọn ní Gómìnà ní Ilẹ̀ Yorùbá (èyí tí ó jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y) wọ̀nyí, pé àkókò tí wọ́n le rí Olórí-Ìjọba-Adelé D.R.Y, tàbí ẹnikẹ́ni ní D.R.Y ti kọjá o! Nítorí náà, kí wọ́n máṣe rò pé D.R.Y máa wá bá’wọn ṣe ìpàdé jíjọ̀wọ́-iṣẹ́-ìjọba sílẹ̀ kankan mọ́ o. Wọ́n ní kí ẹnikọ̀ọ̀kan wọn ó ṣe wọ́ọ́rọ́wọ́ jáde, báyi, kúrò ní ibi tí wọ́n jẹgàba lé yẹn, kí wọ́n rọra ṣe àṣepé jíjọ̀wọ́-iṣẹ́ sílẹ̀ fún alákoso Ètò-Ìṣúná (D.G, Ministry of Finance) àti fún Adájọ́-Àgbà ní Ìpínlẹ̀ náà.
Màmá sì tún sọ fún wọn pé tí wọn kò bá ṣe eléyi, kò sí ìgbà tí wọn ò ní kúrò níbẹ̀ náà o!