Àwọn oníṣòwò ọmọ China kan ti gba ìṣàkóso àwọn ilé ìgbafẹ́ ìjọba Nàìjíría tí ó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì ti ń gbèrò láti tàá, nítorí ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà kò san owó ìtanràn ẹjọ́ tí àwọn oníṣòwò náà pé Nàìjíríà, èyí tí ìdájọ́ sì ti wáyé ní ẹgbẹ̀wa-ọdún-ó-lé-mọ́kan-lé-lógún, látàrí àdéhùn kan tí ó wà láarín ilé-iṣẹ́ China ọ̀ún àti Ìpínlẹ̀ Ògùn nígbàtí Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣì wà ní Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí ó ti wà ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) báyi.
Owó ìtanràn náà dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́ta dọ́là, sùgbọ́n pẹ̀lú àwọn èlé orí ẹ̀ gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin mílíọ̀nù owó dọ́là.
Ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria yí fi ẹ̀gbẹ́ tì Orílẹ̀ Èdè wa Democratic Republic of the Yorùbá, ó sì ń fi ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, ohùn tó jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ìjẹgàba wọn lóri ilẹ̀ wa àti pé ìpínlẹ̀ Ogun yí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ wá ní D.R.Y.
Kí wọ́n má sì ṣe kà wá mọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà mọ́ nítorí gbogbo àgbáyé ti mọ̀ pé ilẹ̀ Yorùbá tí jáde kúrò lára Naijiria láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa nígbàtí a ti búra wọlé fún olórí Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún.
Màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ti sọ pe gbogbo gbèsè tí Nàìjíría bá ki ọrùn bọ̀ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, tí a ti di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira kúrò nínú Nàìjíríà, kò kàn wá.
A yàtọ̀ pátápátá sí Nàìjíríà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tún kà wá mọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni a ti di aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún. Ìlépa tiwa báyìí ni láti ṣídí Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa kíákíá, ìgbésẹ̀ tó dájú sí ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí rẹ̀, láì pẹ́ yii, wọ́n á sáré kúrò lórí ilẹ̀ wa ní yàjóyàjó.