Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́.
Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.
Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.