Ẹ wò bí Nàìjíríà ṣe sọ àwọn ọmọ kéékèèké dà, àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún tí wọn máa ń gbé àwọn ènìyàn lọ pa, tí wọ́n máa yọ kíndìnrín wọn tà fún àwọn tí wọ́n máa tún tà fún àwọn alágbáyé tí wọ́n ń tọ́jú kíndìnrín pamọ́. 

Àwọn ọmọdé wọ̀nyí a máa ta kíndìnrín kan ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀édọ́gbọ̀n naira tí wọ́n á sì ta orí kan ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà owó ìlú apanilẹ́kún jayé nàìjíríà.

Ìròyìn yí jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára X, ohun tí ó bà’nìyàn nínú jẹ́ ní pé, wọn tí fi àwọn ìwà ọ̀daràn wọ̀nyí ba ilẹ̀ D.R.Y. jẹ́, nítorí ìwádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọmọdé kùnrin tí ọwọ́ tẹ̀ náà fi hàn pé agbègbè kan ní ìlú Èkó ni Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), tí ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ń fipá jẹ gàba lé lórí, ní ọmọ náà ń dárúkọ, tí èdè ẹnu rẹ̀ kò sì já gaara, ìyẹn ní wípé, tájá t’ẹran ni ó wá ń f’ara pamọ́ ṣe ìbàjẹ́ ní ìlú Èkó. 

Ìbájẹ́ wípé, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó-lé-mérìn-lé-lógún tí a ti  bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́jọba-ara-ẹni tí a sì ti búra fún Olórí ìjọba Adelé wa ni, àwọn ajẹ gàba ti kúrò lórí ilẹ̀ wá, kí ìbá má ti sí àyè fún gbogbo ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí. 

Àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), ẹ jẹ́ kí á so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa láti tún Orílẹ̀ èdè wa ṣe.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024