Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla máa ń sọ wípé, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé oore ńlá tí Olódùmarè ṣe fún wa ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ( Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní gbogbo ìgbà.

Ọpẹ́ ló yẹ Olódùmarè fún àánú Rẹ̀ lórí wa tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni kí ìran Yorùbá padà sílé tó sì gbé gbogbo ohun tí a nílò láti ṣe àṣeyọrí fún ìyá ìran Yorùbá, màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá.

Àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tó kún fún ìgbá’yé gbá’dùn lorísìírísìí. Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ni yóò rí ògo wọn lò, iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu fún àwọn ọ̀dọ́ wa, kò sí ọ̀dọ́ tó jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) tí kò ní ní ilé lórí nítorí pé láti ọmọ ọdún mọ́kanlélógún ni àwọn alákòóso D.R.Y yóò ti fún wọn ní ilẹ̀ tí wọ́n yóò sì ṣe ìrànwọ́ fún wọn láti kọ́ ilé náà.

Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti wà nílé fún àìmọye ọdún tí wọn ò rí iṣẹ́ ṣe, a kí yín kú oríire. Ìgbà ọ̀tun ti dé, kò sí àìríṣẹ́ mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Ẹ̀ka tí oníkálukú bá ti kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò ti ṣe iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí ojúṣàájú, gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ìrẹ́jẹ nínú ètò ìgbaniṣíṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Ní kété tí àwọn alámòójútó wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa, ní ìpínlẹ̀ méjèèje, oríṣiríṣi iṣẹ́ tí oníkálùkù wa yàn láàyò ni a ó ma ṣe.

Kò sí ìyà fún ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) mọ́, kí a máa gbádùn ló kù.

Emi la ò ní yọ̀ sí àwa ọmọ Yorùbá, a ti dé ibi ìṣe rere wa, ẹ jẹ́ kí a máa jó kí á sì máa yọ̀, a ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, ògo àwọn ọ̀dọ́ wa sì ti búyọ.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates