Láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ní àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá kò ti ní ànfàní kankan ti wọ́n nṣe fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, gẹ́gẹ́bí ìwádìí ìjìnlè tí òrìṣà òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe lóri ipá tí àwọn ọba yí kò nínú ayé ọmọ Aládé, ìyà àti ìrẹ́jẹ ni ipò ọba jẹ́ fún ìran Yorùbá.
Ni akọ́kọ́, kò sí ìdájọ́ òdodo lẹ́nu àwọn ọba náà pẹ̀lú àwọn ìjòyè wọn. Ẹnití ó bá lówó tàbí ipo ní wọ́n máa ngbè lẹ́yìn rẹ̀, tí ènìyàn bá sì jẹ́ gbajúmọ̀ tàbí tó mọ gbajúmọ̀ láwùjọ̀, òfin tàbí ìdájọ́ kìí ṣe lòdì sí irú wọn. Àwọn mẹ̀kúnnù aláìlénìyàn ní idà òfin máa n bà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọba yìí máa n gba ilẹ̀, ilé, oko àti ohun ìní míràn pẹ̀lú agbára, lọ́wọ́ àwọn ará ilu.
Nígbà míràn àwọn ọba ìkà yí á gba ìyàwó lọ́wọ́ ọkọ wọ́n á sì ṣe ìdájọ́ ikú fún ọkùnrin náa. Gbogbo owó ìlú àti ìṣákọ́lẹ̀ ni àwọn ọba àti gbogbo ìjòyè ìlú ma n pín mọ́’wọ́ láì bìkítà fún ará ìlú rara. Ayé fàmí-létè-ki-n-tu-tọ́ tí àwọn ọba yí njẹ pọ̀ gan tí kò ṣe kà tán, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé kò sí ẹnití ó lè mú àwọn.
Màmá wa tún ṣàlàyé pé àwọn ọba yí tún peléke nínú òwò ẹrú ṣíṣè, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ológo ilẹ̀ Yorùbá ni àwọn ọba náà tà ní eru fún àwọn òyìnbó láti gba dígí, agboòrùn, ọtí líle òyìnbó, bàtà, aṣọ, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Òwò búburú yìí wọ̀ wọ́n lẹ́wù dé bi pé nígbàtí àwọn òyìnbó ṣe òfin láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, àwọn ọba yí kò gbà, wọ́n tẹ̀síwájú láti máa ta àwọn ọmọ ìlú lẹ́rú lábẹ́lẹ̀.
Ìwà ìmọtaraẹni nìkan yí fihàn pé wọn kò ní ìfẹ́ ará ìlú rara, ìfẹ́ owó àti ọrọ̀ ayé jẹ wọ́n lógún ju ìfẹ́ ìran ọmọ Yorùbá.
Kí wá ni ànfààní orógbó tí a pa tí kò láwẹ́, tí a jẹ, tó tún korò. Ṣé bí igi tí kò lè dá’ná fún ni yá, tí a bá ko dànù, kò burú, bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rọ̀ àwọn ọba yìí jẹ́. Ní òde òní, àwọn tí olóṣèlú aríremáṣe nàìjíríà npè ní ọba pàápàá kò yàtọ̀ sí àwọn ọba ìṣáájú, àwọn wọ̀nyí wá burú jáì jù àwọn ọba ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Wọ́n ní ìfẹ́ àwọn olóṣèlú, òyìnbó amúnisìn àti Fulani, ṣùgbọ́n wọ́n ò fẹ́ràn ìran ọmọ Yorùbá rárá. Ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóṣèlú àti Fulani, àwọn ọba njí àlùmọ́nì ilẹ̀ Yorùbá àti owó wa lọ sọ́dọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun, wọ́n si nfi ọwọ́ agbára gba ilẹ̀ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá tí wọ́n sì ntàá fún àjèjì.
Aṣemáṣe àwọn ọba yí kò ní ònkà, àwọn fulani darandaran tún san owó fún àwọn ọba ìkà yí láti da ẹran jẹ oko ní ilẹ̀ wa, tí wọ́n sì npa eniyan bí eni npa ẹran.
Pabambarì ibẹ̀ ni pé àwọn amọtaraẹni nìkan tó npe ara wọn ní ọba yìí tún wá dìde lòdì sí òmìnira wa kúrò nínú ètò amúnisìn tí ó jẹ́ agbésùnmọ̀mí àti apànìyàn jayé nàìjíríà. Nítorí owó àti ipò, àwọn ènìyàn búburú tó ńpe ara wọn ní ọba yìí nfẹ́ kí ọmọ Yorùbá tẹ̀síwájú nínú ìṣẹ́, ìyà, òṣì, ebi, àrùn, àìsàn, àìnírètí, ikú òjijì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Nítorí náà nigbati òfin àwọn Fúlàní amùnisìn ti yọ wọ́n kúrò ní ọba, òfin orílẹ̀ èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) kò sì fi àyè gba ipò ọba nítorí kò sí oore tí ìpá wọn ṣe fún ìdí ọmọ Yorùbá, kí oníkálùkù wọn lọ wá iṣẹ́ ṣe.