Òrọ̀ ti jáde o! Àṣẹ sì ti gùn-ún, nípa ilé-ìwé ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyi.
Ṣé tẹ́lẹ̀ ni a tilẹ̀ ti mọ̀ pé, ní Ọjọ́ Kéjìlá, Oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, ni Olórí Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọ́rẹ́, ti fi ohùn síta pé kí gbogbo ilé-ìwé ní D.R.Y ó wà ní títì-pa; ṣùgbọ́n àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọ́n njẹgàba sorí ilẹ̀ wa nṣe bí ẹni tí etí ndùn, wọ́n jóko sí ibi tí a sọ pé kí wọ́n kúrò, ṣùgbọ́n tí wọ́n máa kúrò bóyá wọ́n fẹ́ tàbí wọ́n kọ̀; ṣebí àwọn ni ó kọ etí-ikún sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n ntẹ̀síwájú láti jẹgàba, ṣùgbọ́n bàbá wa, Olórí Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y ti fún wọn ní Ìkìlọ̀-Ìkẹ́yìn ní àìpẹ́ yí, àti pé lẹ́yìn ìkìlọ̀-ìkẹ́yìn yẹn, kò tún sí òmíràn, bí wọ́n bá sì ti ṣe àìgbọ́ran si, àti àwọn àti ìdílé wọn ni ìyà rẹ̀ máa jẹ títí láí.
Kìí wá ṣe èyí nìkan báyi o; gbogbo ọmọ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) tí ó bá nfi ọwọ́so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ajẹgàbá wọ̀nyí náà ni ẹ̀sùn wà ní ọrùn wọn!
Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ní wọ́n gbé ohùn síta nípa èyí! wọ́n sì ti kìlọ̀ báyi, wọ́n pa àṣẹ pé kí gbogbo àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí D.R.Y, kí á mú àwọn ọmọ wa kúrò ní ilé-ìwé ní’bi tí Nàìjíríà ti njẹgàba s’orí ilẹ̀ wa, D.R.Y, ìbáà ṣe ilé-ìwé ti gbogbo-o-gbò tàbí ti aládani, láti alákọbẹ̀rẹ̀ títí dé fásitì: kí á lọ mú wọn kúrò níbẹ̀; ìdí ni pé ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí ó bá fi ọmọ sí ilé-ìwé tí ajẹgàba Nàìjíríà nṣe àkóso rẹ̀, irú I.Y.P bẹ́ẹ̀ ti fi ọwọ́so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú ọ̀tá tó njẹgàba sórí ilẹ̀ wa nìyẹn! Eléyi sì lẹ́yìn!
Kí ẹnikẹ́ni máṣe rò pé Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y kò ní mọ̀! Nígbàtí àwọn Aṣojú wa bá wọ inú Oríkò-Ilé-Iṣẹ́-Ìlú wa gbogbo, wọ́n máa rí àkọsílẹ̀ gbogbo ọmọ tí ó sì nlọ sí ilé-ìwé lábẹ́ ajẹgàba, lẹ́yìn ọjọ́-kẹ́ta oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún tí àṣẹ yí ti jáde!
Gbogbo irúfẹ́ akẹ́kọ bẹ́ẹ̀ ti pàdánù ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) nìyẹn! Bẹ́ẹ̀ ni òbí irúfẹ́ ọmọ náà kò ní ní Ẹ̀tọ́ sí àwọn ohun kan tí ó wà fún Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá!