Afẹ́fẹ́ ti fẹ́, a ti ri ibi tí adìyẹ fi nṣe gá. Ọkùnrin ọ̀daràn kan, Jẹ̀lílì Alégẹ tó pe ara rẹ̀ ní alága ìjọba ìbílẹ̀ Àlímọ̀ṣọ́ ní ipinlẹ̀ Èkó gbé fónrán kan jáde lórí ayélujára “X,” láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn arúfin tó npe ara won ní ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tó nfi agídí jẹ gàba lé lórí.
Ó ní àwọn tó pe ara wọn ní aṣojú-ṣòfin yìí dá òun dúró ní ipò alága nítorí òun kọ̀ láti fa ọjà Ìyànà Ìpájà lé ọ̀wọ́ Abiọdun Ìṣọ̀lá Èjígbádéró, ọkùnrin ajagun gba’lẹ̀ kan nílùú Èkó gẹ́gẹ́bí àṣẹ wọn. Àwọn ìwà ọ̀daràn yìí ní wọ́n ńhù lórí ilẹ̀ wa olómìnira aṣèjọba-ara-ẹni.
Àrífín àwọn arúfin yìí wá npeléke si lójojúmọ́ nítorí ìjẹgàba ìlú apànìyàn ṣayọ̀ nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa. Ìwọ to pe ara rẹ ní alága ìjọba ìbílẹ̀ Àlímọ̀ṣọ́ àti àwọn ọ̀daràn tí n pe ara wọn ní aṣojú-ṣòfin ní Èkó, ṣé ẹ mọ̀ pé ọ̀ràn lẹ̀ ń dá? Ta ló yàn gbogbo ẹ̀yin olè wọnyí sí ipò tí ẹ̀ njà sí l’órílẹ̀ èdè wa?
Àṣírí yín ti tú lórí bí ẹ tí ṣe n jí owó ọmọ Yorùbá tí ẹ̀ sì ńfi ìbọn, àdá pẹ̀lú ìgbójú gba ilẹ̀ àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P).
Gbogbo yín lẹ ma f’ojú ba ilé ẹjọ́ àgbáyé láti jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín. Babájídé Sanwó-olú fúnra rẹ̀ tó jẹ́ aṣojú fún ìjọba agbésùnmọ̀mí ajẹgàba nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Èkó náà yíó káwọ́ sẹ́yìn rojọ́.
Ṣe ẹ kò gbọ́ pé ilẹ̀ Yorùbá kò sí lára ìlú rádaràda nàìjíríà mọ́ ni? Gbogbo àgbáyé ti gbọ́ pé àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti ṣe ìkéde òmìnira wa kúrò nínú ìlú àmú’lé tì wá, agbésùnmọ̀mí nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun tí a sì ti búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nípasẹ̀ iṣẹ́ àṣepé tí Olódùmarè lo màmá wá Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti ṣe.
Orílẹ̀ èdè olómìnira aṣèjọba-ara-ẹni ní D.R.Y, nítorínáà, àwa I.Y.P ń sọ fún ìjọba búburú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa kí àwọn Adelé wa lè wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa. Bí ẹ bá kọ̀, ẹ ó kan ìdin nínú iyọ̀ láì pẹ́ yìí.