Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé.
Àwọn bàbá wa á máa sọ wípé “Ìfura l’òògùn àgbà, páńsá ò fura páásá já síná, àjà ò fura, àjá jìn, onílé tí ò bá fura, olè ni ó ko lọ”.
Òwe Yorùbá
Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yoruba, ẹ jẹ́ kí a máa fura o. Gbogbo àwa ọmọ Yorùbá mọ̀ wípé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ àwọn baba ńlá wa, ewéko, eran ọ̀sìn, adìẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XBill Gate so wípé kí wọ́n máa dẹ́kun màlúù ní dídà àti wípé màlúù tí ó ń jẹ ewéko ń ṣe àyípadà bá ojú ọjọ́, tí kì dẹ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Ka Ìròyìn: Bill Gates – Ìránṣẹ́ Apànìyàn Tí Àṣìtáánì Nlo Lati Ṣe’Jàǹbá Fun Aláwọ̀dúdú
O sọ wípé àwọn tii ń ṣe ìwádǐ àti wípé àwọn ní àjẹsára ọ̀fẹ́ láti máa gbé màlúù jáde láti inú ilé iyàrá ìwádǐ wọn.
Èròńgbà wọn ni láti ṣe ìrọ́pò ẹran tí ó dára tí ó ń jẹ ewéko tí ó ń ṣe ara àwọn ẹran náà àti ènìyàn ní àǹfànní, pẹ̀lú àwọn ẹran màlúù tí wọ́n ń dàgbà nínú ìyàrá ìṣèwádǐ ti wọn.
Ẹ jẹ́ kí a máa fura, kí á sì má gba eléyìí láàyè rárá nítorí àwọn oríṣiríṣi kẹ́míkà tí wọ́n ń pòpọ̀ nínú ìyàrá ìwádǐ wọn tí wọ́n ń fún àwọn ẹran màlúù náà, tí ó sì jẹ́ ìpalára fún àwọn ẹran náà àti èèyàn pẹ̀lú.
Ẹ jẹ́ kí àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá máa jẹ oúnjẹ, ẹja, ẹran-ọ̀sìn, àti ohun ọ̀gbìn gbogbo tí ó ń ṣe ara ní àǹfànní àti pàápàá oun tí ó máa ṣe ara eni ní pípé pẹ̀lú óúńje àdáyébá láì sí àbùlà kẹ́míkà kankan.
Èyí ni l’ara ètò rere tí ó wà nílẹ̀ fún gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.
Ka Ìròyìn: Ààrẹ Senegal Mú Owó Ìrìnnà Kúrò Ní Àwọn Onjẹ Tí Ó Nwọlé Sí Ìlú Rẹ̀