Etí ẹ mélo, ọmọ Yorùbá?

Tí o kò bá ìtíìgbọ́ tẹ́lẹ̀, ṣíra, báyi, k’óo gbọ́! Arákùnrin òyìnbó kan wà tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Bill Gates. Apànìyàn ni. Ibik’ibi tí o bá ti gbọ́ orúkọ ẹ̀, kí o má ṣe gbàá l’aàyè l’ati ṣe iṣẹ́ ibi ẹ̀.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X


The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Bill Gates ní ìgbàgbọ́ wípé ọmọ ènìyàn tí ó wà nínú ilé ayé yí ti pọ̀jù, àti wípé òun àti àwọn bí ti òun máa ri wípé wọ́n dín iye ọmọ ènìyàn tí ó wà nínú ayé yi kù.

Ka Ìròyìn: Àwọn Òyìnbó, Aláyébàjẹ́ Ni Wọ́n

Ní’gbà covid-19, Bill Gates pẹ̀lú àwọn t’ó wà ní’dí ẹ̀! Wọ́n mọ̀ọ́ mọ̀ da aìsàn náà sí’ta l’ati pa ọmọ ènìyàn ni. Iṣẹ́ àwọn òyìnbó tí wọ́n fẹ́ gba ilẹ̀ Afríkà ni.

Bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé gbogbo àgbáyé ni wọ́n fẹ́ máa dà ríborìbo, sí’bẹ̀, ìlẹ̀ aláwọ̀dúdú ní pàtàkì, àti àwa èèyàn aláwọ̀dúdú ní pàtàkì jùlọ ni wọ́n fẹ́ kó kúrò nlẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ pawámọ́ kúrò nlẹ̀, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè kò ní jẹ́.

Ka Ìròyìn: Susan Rice Purọ́ Nínú Ìwé Rẹ̀ Nípa Ikú MKO Abíọ́lá

Ṣùgbọ́n, má ṣe fi ẹnu nìkan sọ́ wípé Olódùmarè kò ní jẹ́: o níláti ṣiṣẹ́ tọ̀ọ́ ni!

Oun ibi tí Bill Gates àti àwọn bíi tirẹ̀ tún nṣe, báyi, ni wípé, wọ́n fẹ́ pa ọmọ ènìyàn, ní pàtàkì jùlọ, ọmọ Afríkà, nípa sí sọ wípé kí àwọn ènìyàn má ṣe gbin ohun ọ̀gbìn àdáyébá wa mọ́, gẹ́gẹ́bí àgbàdo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bill gate plan to depopulate Africa. Yoruba Nation latest news

Dípò eléyi, wọ́n a fún wa ní àgbàdo àti ohun ọ̀gbìn míràn gbogbo tí kìí ṣe èyí tí Ọlọ́run dá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ èyí tí àwọn Bill Gates àti àwọn bíi tirẹ̀, tí wọ́n ṣe fún’ra wọn ní’bi ìpamọ́ ìjìnlẹ̀ wọn; wọ́n á sì máa ta èyí fún wa géégẹ́bí ohun tí a máa máa jẹ, tí a sì máa máa sìn; ṣùgbọ́n àgbàdo sàtáánì yí, àti irúfẹ́ ohun ọ̀gbìn bẹ́ẹ̀ míràn, jẹ́ èyí tí wọ́n ti fi oró sí l’ara, tí ó jẹ́ wípé, ìṣe’kúpani ni ó wà fún.

Ka Ìròyìn: Àwa Ojúlówó Ọmọ Òmìnira Yorùbá Àtàtà Kìí Ṣe Ajìjàgbara Mọ́ Ooo

Wọ́n ní ojú l’alákàn fi nṣọ́’ri, àbí bẹ́ẹ̀ kọ?

Èyí tí gbogbo nkan wọ̀nyí tú’mọ̀ sí ni wípé, a kò gbọ́dọ̀ gba irúgbìn k’irúgbìn kankan l’ọdọ̀ ẹnik’ẹni, ìbáà ṣe àwọn ìjọba Nigeria tí ó fi ipá dúró l’orílẹ̀ wa ni, tàbí ẹnik’ẹni tí ìbáàwù k’ó jẹ́, tí wọ́n bá ni kí à wa ra àwọn irúgbìn wọ̀nyí.

Ẹ jẹ́ kí inkan ìbílẹ̀ wa tí a ti njẹ l’ati ayébáyé kí ó tó wa.