Oríṣiríṣi ọbẹ̀ là ń rí lọ́jọ́ ikú erin. Láìpẹ́ yìí ní a gbọ́ wípé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ọmọ Yorùbá kan tí wọ́n pe’ra wọn ní Ìgbìmọ̀ Májẹóbàjẹ́ Ilẹ̀-Yorùbá, ni wọ́n ti ń ké ìbòsí ebi àti ìyàn báyìí tí wọ́n sì ń pe ààrẹ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà wípé kò kọ̀’wé fi’pò sílẹ̀.
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá wa béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ yí, pé, ṣé etí wọn di, wọn ò gbọ́ pé ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ara Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, àti pé a ti ní ìjọba tiwa ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún?
Ṣé etí wọ́n di, wọn ò gbọ́ pé ìjọba D.R.Y ti fagilé gbogbo ẹgbẹ́, pátá, ní ilẹ̀ Yorùbá?
Tó bá jẹ́ l’oótọ́, ọ̀rọ̀ Yorùbá jẹ yín lógún, ó yẹ k’ẹ ti máa tẹ̀lé gbogbo bó ṣe nlọ ní ilẹ̀ Yorùbá, kí ẹ dẹ̀ ti mọ̀ pé Yorùbá yàtọ̀ sí Nàìjíríà pátápátá. Nípa pípe Yorùbá mọ́ Nàìjíríà, ọ̀ràn ni ẹ ti dá yẹn, àti pípe ara yín ní ẹgbẹ́, jẹ́ ọ̀ràn dídá lábẹ́ òfin D.R.Y.
Ìwọ Olúṣọlá Olúwáṣèyí Bádéró, tí o pe’ra rẹ ní Olùkójọ ẹgbẹ́ tó lòdì sí òfin Orílẹ̀-Èdè Yorùbá yí, mọ̀ dájú pé arúfin àti ọ̀daràn l’o jẹ́ lábẹ́ Òfin Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Kìí tún wá ṣe ìyẹn nìkan ó, ṣùgbọ́n àwọn ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ yí sọ pé kí ààrẹ agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, ìlú tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá ṣùgbọ́n tí ó njẹgàba lórí ilẹ̀ wa, wọ́n ní kí ó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ àlè Yorùbá tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ìlú aríremáse Nàìjíríà wọn lọ́hùn-ún nítorí pé ààrẹ wọn Tinubu ọ̀ún kò tilẹ̀ bìkítà nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ rárá, ṣe ló túbọ̀ ń ṣe òfin tó ń fi ara ni ará ìlú wọn lójoojúmọ́. Ìwọ Olúṣọlá Olúwáṣèyí Bádéró, mọ̀ dájú pé oò lè bọ́ nínú èyí tí o kó sí yí o, tí o nka orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, D.R.Y, mọ́ Nàìjíríà, tìẹ ti bá ẹ, o ò lè rùúlà!
Èyí tó pe ara rẹ̀ ní Olusọla Oluwaseyi Badero yí, fi ohùn síta, ó wípé, ọmọlúwàbí ni a mọ ìran Yorùbá sì, ṣùgbọ́n ìnira tí ìṣèjọba Ààrẹ Nàìjíríà, Tinubu, mú bá wọn ti sọ oníkálukú di alágbe. À bẹ́ẹ̀ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ wèrè; níbo ni ìwọ Bádéró àti àwọn wèrè tó-o kó ti’ra wà nígbàtí ilẹ̀ Yorùbá wà lóko ẹrú? Yorùbá wá dúró tán gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè tí ó ní Ìjọba tirẹ̀, wèrè yín wá jáde pé ẹ ní ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ kan! Ẹ rò pé eré ni, àbí? Ẹ npàdí àpò pọ̀ mọ́ Nàìjíríà láti ka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ Nàìjíríà, àbí? Áá tó yé yín.
Àwọn ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ yí sọ pé, ní àkokò tí wọ́n ń ṣe ìpolongo ìbò ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Tinubú ṣe ìlérí pé òun yóò dín owó epo pẹtiró kù, ṣùgbọ́n ní kété tó wọlé báyìí ni ó tún fi kún un láì sọ fún ẹnikẹ́ni rárá. Ẹ̀yin wèrè, Yorùbá ti jáde kúrò lára Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, kí Nàìjíríà ó tó dìbò! Nítorí náà, kí lẹ nsọ lẹ́nu?
Àwọn wèrè ọ̀ún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ wọn wípé, àwọn ará ìlú kò leè rán ọmọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rí oúnjẹ jẹ ti àpò ìrẹsì kan sì ti di ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin náírà báyìí. Ṣé ilẹ̀ Yorùbá ṣẹ̀ṣẹ̀ bàjẹ́ ni, ẹ̀yin alákọrí? Níbo lẹ wà kí ó tó di ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún tí Yorùbá jáde kúrò nínú Nàìjíríà, nípasẹ̀ iṣẹ́ tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe? Níbo lẹ wà kó tó di ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a gbé ìjọba D.R.Y wọlé
Wọ́n ní Tinubu kò ní ìmọ̀ bí yóò ti ṣe ìjọba ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà mọ́,kó fi ipò náà sílẹ̀. Ẹẹn, Nàìjíríà nìyẹn-ẹ̀n, ẹ kọjá sí Nàìjíríà-à!
Wèrè alákọrí wọn wá ń rọ àwọn ènìyàn láti jáde fún ìfẹ̀hónúhàn tí wọ́n ní àwọn fẹ́ ṣe ní oṣù tó ń bọ̀ yí. AH!! Ọmọ Yorùba kankan, ẹ má danwò, pé ẹ fẹ́ bá wọn ṣe ìwọ́de-Naìjíríà kankan, tàbí ìfẹ̀hónúhàn Nàìjíríà kankan ní ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba! Ẹni tí fọ́tò tàbí fídíò bá ti gbé ojú ẹ̀ jáde pé ó kópa nínù ẹ̀, ó ti kó bá ara ẹ̀ àti ìdílé ẹ̀, láíláí, ní ilẹ̀ Yorùbá!
Ìjọba-Adelé ti wà ní ìkàlẹ̀ ni D.R.Y, abẹ́ ìjọba Adelé ni gbogbo wa wà, a ò sí ni Nàìjíríà mọ́. Nígbàtí màmá wa MOA sọ nígbànáà lọ́hun pé nkan tó mbọ̀ ẹ̀mí wa ò ní lè gbe, ẹ̀yin ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ yí ò gbọ́ran nígbà yẹn. Èyí tí ẹ̀ bá fi ọwọ́so-‘wọ́pọ̀ pẹ̀lú wa, kí a gbé ìjọba D.R.Y wọlé ní kiá nígbàyẹn l’ọhún, ẹ kọ etí ọ̀gbọin sí ọ̀rọ̀ náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn wèrè tí wọ́n ní “Yoruba Nation” l’àwọn gbé dání nígbà náà, tí ó sì jẹ́ pé, irọ́ ni, ọ̀dọ̀ àwọn olóṣèlú ní wọ́n darí àwọn ọmọ Yorùbá kan sí nígba yẹn, tí wọ́n dalẹ̀. Gbogbo yín nígbà yẹn l’ọhún, àwọn olóṣèlú nàìjíríà ni ẹ tẹ̀ lé, èyí tí ẹ̀ bá gbárùkù ti iṣẹ́ tí Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá gbé dání, ká lè tètè dé’bi tí a nlọ.
Ẹ ṣorí-kunkun nígbà yẹn, àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí wọ́n ní Yorùba Nation l’àwọn nṣe nígbà náà, tó dẹ̀ jẹ́ irọ́, nṣe wèrè kiri títì nígbà náà; ó wá njó yín báyi, ẹ nsọ’sọ-kúsọ! Ẹ wá fẹ́ gbowó lọ́wọ́ Tinúbú báyi ẹ ní ẹ fẹ́ ṣe ìwọde?! Ọmọ Yorùbá, ẹ má bá wọn dan wò!
Bí ẹ ṣe ṣe nígbà tí ẹ sọ pé ẹ nṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní ìlú agbésùnmọ̀mí ajẹgàba Nàìjíríà yín lóṣù tó kọjá nìyẹn, tó jẹ́ pé ọ̀nà àti gba owó lọ́wọ́ Nàìjíríà náà ni, Nàìjíríà tó njẹgàba lórí ilẹ̀ D.R.Y. Bí ẹ ṣe máa nṣe nìyẹn, láti fi wá òkìkí.
Tí ẹ bá ti fẹ́ gbowó lọ́wọ́ agbésùnmọ̀mí nàìjíríà lẹ máa nṣe ìwọ́de òṣì yín kiri ní nàìjíríà ìlú ajẹgàba ọ̀ún. Kí ẹ yára mọ̀, báyi, pé, ọ̀ràn gidi ló já sí, tí ẹ bá dáwọ́ lé ìwọ́de kankan ní ilẹ̀ Yorùbá. Ẹ fẹ́ fi ìwọ́de dẹ́rùba Nàìjíríà ìlú agbésùnmọ̀mí, wọ́n á wá gbé owó fún yín láti lè pa’ná ẹ̀, iṣẹ́ yín nìyẹn, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe dába ẹ̀ lórí ilẹ̀ Yorùbá.