Àwọn ọ̀daràn arúfin kan tí wọ́n pe’ra wọn ní ẹgbẹ́ “Think Yoruba First” ni wọ́n ti ṣe lòdì sí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) nípa pípe Orílẹ̀-Èdè D.R.Y ní ara aríremáse Nàìjíríà, èyí tó lòdì pátápátá sí ìkéde Òmìnira D.R.Y ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún.
Ẹgbẹ́ “Think Yorùbá First” yí tàpá sí òfin àti àṣẹ tó ti ẹnu olórí ìjọba Adelé D.R.Y jáde, nípa pípe ara wọn ní “Ẹgbẹ́” lẹ́yìn tí Olórí-Adelé ti sọ pé a fagilé gbogbo ẹgbẹ́ ní kété tí ìjọba D.R.Y gun orí àlééfà ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Ìwà kíkọlu ìjọba D.R.Y yí wáyé látàrí ohun tí àwọn tó pe’ra wọn ní “Think Yorùbá First” yí gbé jáde nípa bí wọ́n tì ṣe ń ka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ara ìlú ajẹgàba Nàìjíríà.
A gbọ́ pé, ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà yan ìgbìmọ̀ kan láti gbé àbá kan kalẹ̀ lórí dída ẹran jẹ̀ ní gbangba,wọ́n ní èyí yóò mú àlàáfíà wà ní ìlú wọn lọ́hùn-ún, kò sì ní sí ìjà àti ipaniyan mọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega ni alága ìgbìmọ̀ náà. Lẹ́yìn ìwádìí wọn, ohun tí wọ́n gbé jáde ní pé, kí àwọn ọmọ ìlú wọn fún àwọn Fúlàní ni ọdún mẹ́wàá síi láti tún fi da ẹran ní gbangba.
Èyí ni àwọn tó pera wọn ní “Think Yoruba First” yí wá nfèsì sí, tí wọ́n wá pe ara wọn ní ẹgbẹ́ Yorùbá, àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), kò mọ ẹgbẹ́ kankan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ìròyìn náà kò kàn wá, ṣùgbọ́n, torí orúkọ Yorùbá tí àwọn ẹgbẹ́ náà pe ara wọn ni a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwa kò ní ẹgbẹ́ kankan mọ́ ní Orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y.), gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí olórí adelé wa sọ wípé kí gbogbo ẹgbẹ́ tó bá wà tẹ́lẹ̀ di títúká.
Ìlú agbésùnmọ̀mí ńàìjíríà ìbáà fi ogún ọdún kún àkókò tí wọ́n fẹ́ da ẹran ní gbangba, kò kan àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.) tí D.R.Y. Àwa ti g’òkè odò k’áfárá wọn ó tó já.
Orí Ayélujára X ni a ti rí ìròyìn náà, lórí ìkànnì kan tí wọ́n pe ní “The Yoruba Times,” èyí tí ó jásí pé àwọn wọ̀nyí náà ṣe lòdì sí orílẹ̀ èdè D.R.Y, nítorí pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, “Ìròyìn Ojoojúmọ́, ÒMÌNIRA IYPDRY” nìkan ni Ìwé Ìròyìn tó wà ní D.R.Y.
A ò mọ ẹni tó wà ní’dí “The Yorùbá Times” yí, ṣùgbọ́n obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dókítà Bùkọ́lá Adeniji ni ó bu’ wọ́-lu ìkéde tí “Think Yoruba First” gbé síta gẹ́gẹ́bí “Akọ̀wé Àgbà” ẹgbẹ́ náà, tí wọ́n sọ pé àwọn ń sọ̀rọ̀ fún gbogbo ọmọ Yorùbá ní ìlú apanilẹ́kún jayé nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ sì ré, a ò rán wọn níṣẹ́, a ò sì sí lára agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà mọ́.
Ọpẹ́ ńlá ní fún Olódùmarè tí ó rántí ìran Yorùbá sí rere tó wá gbé màmá wa, Olóyè Ìyáàfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá dìde ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí wípé àkókò tó kí a padà sí orísun wa.