Tí Olódùmarè bá ti ṣí’jú wo’ni, àyọ̀ ayérayé ni ó máa njẹ́! Olódùmarè ti sí’jú wo ọmọ-Yorùbá ní àkókò yí, títí òpin ayé, nípasẹ̀ iṣẹ́ tí Ó fi rán Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá sí àwa Ìran Yorùbá. Èyí ni ó dífá fún ọ̀rọ̀ tí Màmá wa bá wa sọ nípa àwọn tí ó pera wọn ní ọ̀mọ̀wé tàbí ọ̀làjú, tàbí àlákọ̀wé, tí wọ́n tún máa nka ara wọn sí gbòógì nínú-ìlú (elite), ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé àwọn ni irin-iṣẹ́ lọ́wọ́ òyìnbó-amúnisìn!
Àfi kí Olódùmarè kí ó gbà wá! Nígbàtí òyìnbó-amúnisìn, Lord Macaulay, sọ nígbà náà l’ọhún pé nṣe ni kí àwọn ṣẹ́ eegun-ẹ̀yìn àwa aláwọ̀dúdú nípa gbígba ohun àdáyébá wa lọ́wọ́ wa – ohun-àjogúnbá wa, jíjẹ́-ẹni-ẹ̀mí tí a jẹ́, àti ẹ̀kọ́ wa tí ó ga, tí ó lágbára, tí ó sì ti wà láti ayébáyé, tani ó mọ̀ nígbà-náà pé irín-iṣẹ́ tí wọ́n máa lò ni àwọn tí a kà sí “ọ̀mọ̀wé,” “ọ̀làjú” tàbí “alákọ̀wé” lóni!?
Nṣe ni àwọn òyìnbó wọ̀nyí kọ́kọ́ mú agbára-àwọn-ọ̀ba kúrò! Lẹ́yìn èyí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ńkọ́ àwọn ènìyàn wa ní ohun tí a mọ̀ sí “ẹ̀kọ́ òyìnbó” láì mọ̀ pé wọ́n fẹ́ fi gba àṣà, ìṣe, ọgbọ́n-àjogúnbá wa, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ!
Àsẹ̀yìn-wá-Àsẹ̀yìn-bọ̀, nṣe ni wọ́n kọ́ àwọn tí a npè ní alákọ̀wé wọ̀nyí LÒDÌ sí ohun-gbogbo tí ó jẹ́ ògo ọmọ-Yorùbá, àwọn wọ̀nyí wá di òyìnbó-aláwọ̀-dúdú ní àárín wa, tí a wá nwò wọ́n lókè-réré bíi pé àwọn ni igbá-kejì Ọlọ́run, tí àwọn náà wá ńrú apá s’okè! Nípa ẹ̀kọ́ tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí kó àwọn “alákọ̀wé” wọ̀nyí,
jẹ́kí àwọn náà wá sọ’ra wọn di ẹni tí ó kórira àṣà Yorùbá, ìṣe Yorùbá, onjẹ Yorùbá, aṣọ Yorùbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ – wọ́n sọ ara wọn di òyìnbó-amúnisìn láarín ọmọ-Yorùbá, wọ́n ńwò àwọn ọmọ Yorùbá tó kù gẹ́gẹ́bí olórí-burúkú, aláì-ní-ìmọ̀, àti ẹni tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àwùjọ.
Nípasẹ̀ eléyi, àwọn òyìnbó-amúnisìn ṣọ-ọ́ di ohun-ìtìjú láarín àwùjọ-Yorùbá láti máa sọ èdè Yorùbá! Bẹ́ẹ̀ sì nìyí, nínú èdè-wa ni orísun-agbára ìdàgbàsókè àti ìṣe-rere wa wà!
Nípasẹ̀ àwọn bọ̀rọ̀kìní-olóyìnbó-dé wọ̀nyí ni ọmọ-Yorùbá fi wá kórira ohun tí ó jẹ́ ti ìṣẹ̀dálẹ̀, àṣà, àti àdáyébá Yorùbá! Bí àwọn òyìnbó-amúnisìn ṣe ṣẹ́ eegun-ẹ̀yìn àwa ọmọ-Yorùbá nìyẹn, tí kìí bá ńṣe ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tí ó ṣí’wa ní iyè, nípasẹ̀ Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí wọ́n ní kí á padà sí Orísun wa tí a bá fẹ́ ní Òmìnira òtítọ́, tí wọ́n sì fi yé wa pé inú ìdè ni a wà tẹ́lẹ̀; ojú ti wá là báyi o! Kò sí nkan tó ńjẹ́ bọ̀rọ̀kìní-olóyìnbó-dé ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) àti pé gbogbo àwa ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ni ológo.
Aṣọ ti tú kúrò lójú eégún o! À ṣé irin-iṣẹ́ amúnisìn ni àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní “elite” wọ̀nyí! Ojú olè rèé! Olè amúnisìn da olè alákọ̀wé-òyìnbó sí ìgboro-ọmọ-Yorùbá láti gba ohun dídára tí ó wà lọ́wọ́ wa, kí á lè sọ ohun iyebíye tí Olódùmarè fún wa sọnù!
Ọ̀rọ̀ kòì tíì tán lórí irin-iṣẹ́ amúnisìn tí wọ́n pera wọn ní “elite” yí o, a ṣìṣẹ̀ ńmú ẹyẹ bọ̀ lápò ni!