Ní Orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y, gbogbo wa la mà mọ ẹ̀tọ́ wa, a kò ní jìyà ǹkankan ní ilẹ̀ wa. Nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso D.R.Y ìkan nínú àwọn ohun tí àwọn Alákòóso wa yíó tètè ṣiṣẹ́ lé ni mímọ ẹ̀tọ́ ẹni gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P
Màmá wá, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla (MOA) ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí láti ṣe àlàyé díẹ̀ fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I Y.P) lára àwọn ìgbádùn aláìlẹ́gbẹ́ tó wà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa ti Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ fún ìran àwa ọmọ Aládé, nítorí tí a bá mọ ẹ̀tọ́ wa, a ó lè ṣe ojúṣe wa fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè wa.
Lára àwọn ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́bí I.Y.P ni ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti ilé ìwé àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ títí dé àkọ́kọ́ gboyè ní Fásiti, ilé ìwòsàn ọ̀fẹ́, iṣẹ́, óńjẹ tó dára lásìkò, iná mọ̀nàmọ́ná tó dúró déédéé, àbò̀ tó péye, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Kòṣemánìí ni iná mọ̀nàmọ́ná jẹ́ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè D.R.Y. nìpa ọrọ̀ ajé, ìlera, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìṣẹ́ ìwádìí, ààbò ẹ̀mí àti dúkìá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ kí ìgbé ayé rere lè wà fún gbogbo D.R.Y.
Gbogbo ètò fún ẹ̀tọ́ àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni olórí Alákòóso wa, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ àti àwọn alákòóso wa tókù nṣiṣẹ́ lori rẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìlú míràn, a ó sì bẹ̀rẹ̀ ìgbádùn lọ́gán tí wọ́n bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa láì pẹ́ jọjọ yìí.
Orílẹ̀ Èdè Democratic Republic of the Yoruba kò ní fi ẹ̀tọ́ àwa Indigenous Yoruba People dù wá, gbogbo wa ni a ó ma gbádùn ní orí ilẹ̀ wa. Ayé wa tí dára.
ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀
Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́. Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.
Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.