Tí ò bá sí olè ilé, olè ìta kò le jà! Ọ̀rọ̀ yí ló dífá fún bí àwọn amúnisìn ṣe lo àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní gbajúmọ̀ ilẹ̀ Yorùbá láti máa tako òmìnira ilẹ̀ Yorùbá.
Wọ́n kọ́kọ́ da àwọn gbajúmọ̀ yí ní ọpọlọ rú, wọn jẹ́ kí wọ́n rò wípé ohun gbogbo tó bá ti jẹ́ ti àwọn amúnisìn ló dára jù. Àwọn alákọrí náà wá bẹ̀rẹ̀ ìgbéraga.
Tí ẹnikẹ́ni bá sọ èdè Yorùbá ní etí wọn, wọ́n á ní kíni ẹni náà ń sọ, ṣé kò rí’ta ni? Wọ́n á ní èdè àwọn ará abúlé ni. Kai! Èdè babańlá wọn wá di ohun tí wọ́n ò fẹ́ gbọ́ létí wọn.
Bí wọ́n ń lọ sóde àríyá tàbí ibi iṣẹ́, wọn ò kí ńwọ aṣọ ìbílẹ̀ Yorùbá, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n a so okùn m’ọ́rùn bí ajá.
Oúnjẹ ìbílẹ̀ Yorùbá wá di oun ìríra, ó tẹ́wọnlọ́rùn kí wọ́n jẹ oúnjẹ tí wọ́n kó wá láti ilẹ̀ òkèèrè. Ikún ń j’ọ̀gẹ̀dè, Ikún ń rèdí, Ikún ò mọ̀ p’óhun tódùn ló ń pani.
Àwọn wọ̀nyí ni amúnisìn ń lò, wọ́n wá rí ara wọn bí ẹni pàtàkì láwùjọ, ohun tí ó bá ti ẹnu wọn jáde ni àwọn ènìyàn ń gbọ́. Iṣẹ́ tí amúnisìn bá rán wọn ni wọ́n ń jẹ́.
Gbogbo ọ̀nà ni wọ́n ń gbà kí ìran Yorùbá máa bàa bọ́ lóko ẹrú. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbógun ti àwọn tó ń jà fún òmìnira àwa ọmọ Aládé.
Wọn o lẹ́nu ọ̀rọ̀ nítorí ìjẹkújẹ tí wọ́n ti jẹ, gbogbo wọn ló ti jẹ dòdò, ó ti di ẹ̀ẹ̀wọ̀ láti sọ òdodo.
Ṣùgbọ́n àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán ẹni bí ọkàn Rẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla sí wa láti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn apanilẹ́kún jayé. Ní gbogbo ìgbà ni màmá wa MOA máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo I.Y.P ló máa lówó lọ́wọ́, kò ní sí òtòṣì mọ láàárín wa afi àwọn tí wọ́n bá ti dalẹ̀ ìran Yorùbá.