Ànfààní tí ó wà fún Ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) kò lónkà! Tí a bá ní kí a máa wòó lọ́kan-ò-jọ̀kan, ọpẹ́ lóyẹ kí á máa dá lọ́wọ́ Olódùmarè tí Ó gbé Àlàkalẹ̀ Rere fún Ìran Ọmọ Yorùbá, tí Ó sì tún wá jínkí wa pẹ̀lú Olùgbàlà, Màmá Rere, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, nípasẹ̀ ẹni tí ó la wá lójú, tí ó sì ńtí ọwọ́ wọn tọ́ wa sí ọ̀nà.
Lára ànfààní tí ó wà fún I.Y.P ti D.R.Y, kò sí ọmọ-òrukàn tí ìyà máa jẹ! Ọmọ òrukàn tí ìwádìí bá fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ́ ojúlówó ọmọ Yorùbà, ìtọ́jú tó péye ma wà fún títí yóò fi ṣe àṣeyege.
Kádúpẹ́ lọwọ màmá wa MOA fún ìrètí tí wọ́n fún àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbà (I.Y.P).
ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀
Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́. Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.
Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.