Nínú fọ́nrán kan tí a fi hàn wá, ní ibi tí àwọn aláwọ̀ funfun kan tí ń ṣe ìpàdé nípa àtúntò ọrọ̀ ajé àgbáyé tí wọ́n sọ pé, àkókò ti tó bàyìí láti gbé ìgbésẹ̀ lórí bí àyípadà ọrọ̀ ajé yóò ṣe tàn kiri ayé pàápàá júlọ ní Amerika,

ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti China. Àwọn kan tí o pe’ra wọ́n ní G-20 ni ó wà ní ìdí ọ̀rọ̀ náà. Ogbọ́n láti kó ọrọ̀ agbáyé sí ọ̀dọ́ ara wọn, kí orílẹ̀-èdè Áfríkà leè tẹ̀síwájú nínú oko ẹrú aláwọ̀ funfun ni.

Gẹ́gẹ́ bí alága ètò okòwò ọrọ̀ ajé àgbáyé náà ṣe sọ̀rọ ó ní, ó jẹ́ dandan báyíì kí ètò tuntun náà kárí ayé, àti pé , àwọn ọ̀dọ́ ni yóò jẹ́ kí ń kàn wọ̀nyì ṣeé ṣe ní kíá. Alága náà sì dárúkọ olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àná, Ríshi Sunak Starmer àti àwọn bíi ti wọn ní àgbáyé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò sí nínú ẹgbẹ́ òsèlú kan náà.

Ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modupẹọla Onitiri Abiọla má ń sọ ni èyí pé ọgbọ́n ìyapa ati idari ẹni fún èrè ara wọn ní ó kún inú àwọn amúnisìn yí, ṣugbọ́n Olódùmarè tí gbé awa Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba D.R.Y) borí ètekéte wọn, nípa bí a ti ṣe di orílẹ̀-èdè olómìnira ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, a sì ní àṣẹ láti ṣètò ọrọ̀ ajé wa lọ́nà tí ó wù wá, nítorí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, ètò ìṣèjobà orílẹ̀ èdè wa sí ti bẹ̀rẹ̀, nítorínáà, màmá wa yìí tí Olódùmarè lò fún òmìnira wa sọ fún wa pé kò sí àyè fún orílẹ̀ èdè kankan láti fí ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé tàbí ohun míràn kò wa lẹ́rú mọ́, àwa D.R.Y tí di orílẹ̀ èdè olómìnira aṣèjọba ara ẹni.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ìyá wa tún jẹ́ ka mọ̀ pé ìkórajọ àti ìpàdé àwọn aláwọ̀ funfun yìí dá lórí ìmúnisìn àti ìjẹgàba, gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá níláti kíyèsára gidi. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ I.Y.P, àsìkò ti tó fún yín láti  rí ògo yín lò, kí ẹ lè ní ọjọ́ ọ̀la tó dára àti ọjọ́ iwájú tí ó dájú, kí wọ́n má sì bàá jẹ yín m’áyé.

Tí a bá sì ṣe àkíyèsí kan nínù fọ́nrán náà, ni ibi tí àwọn oyinbo yìí tí ń ṣe àpérò bí àkọ̀tun ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ káàkiri ayé, kò sí ènìyàn dúdú kan soso níbẹ̀, èyí jẹ́ ọgbọ́n ìkónilẹ́rú tí ìyá wa rí, tí wọ́n fi sọ wípé, ọ̀mọ Yorùbá kò ní ṣe ẹrú mọ́, ètò ọrọ̀ ajé wa yóò sì dúró déédéé, nígbàtí a bá ti bẹ̀rẹ̀ síí lo àlàkalẹ̀ ìṣèjọba wa tí Olódùmarè gbé fún màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla fun ìṣe rere àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, lẹ́yìn tí a bá ti lé àwọn àjẹgaba agbésùnmọ̀mí Naijiria kúrò lórí ilẹ̀ wa, tí àwọn ìjọba Adelé wá sì ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ní kíákíá láì pẹ́ yìí, a ó wá di àwòkọ́ọ̀se fún orílẹ̀-èdè Áfríkà àti káàkiri àgbáyé.