Alátakò ohun rere, pàápàá ẹni tó ntako ìran rẹ̀, kò lè ṣe rere. Ẹ̀gún ayérayé ló máa wà lóri ẹni náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀.

Ọ̀rọ yí dá lórí àwọn tó ń tako iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe fún àwa I.Y.P ti D.R.Y, tí wọ́n ń tako Ìṣàkóso Adelé, àti D.R.Y. Dájúdájú, àgbékalẹ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ń ṣe àtakò fún. 

Ìránṣẹ́ Olódùmarè fún ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), Ìyá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), kọ́jú ọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ tí wọ́n ń pe ara wọn ní ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, pé, wọ́n jẹ́ alátìlẹ́yìn fún àwọn alátakò ìran Yorùbá. Màmá wa sọ kedere, pé, iṣẹ́ ibi àwọn òbàyéjẹ́ náà pọ̀ gan, ẹ̀rí gbogbo rẹ̀ sì wà nílẹ̀. 

Àwọn alátakò náà gbàgbọ́ pé iṣẹ́ ìyá wa, MOA, ni àwọn ń takò, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni.

Ẹnikẹ́ni kò lè ṣe ohun tó lágbára tó báyìí. MOA tẹ̀síwájú pé Ọlọ́run ló fún àwọn ní ẹ̀bùn láti ṣe àṣeyọrí nínú ìrìn àjò náà, tó sọọ́ di Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Àtúnbọ̀tán àwọn alátakò ohun-rere fún ìran, kìí dára. Búburú ma njá lu búburú fún wọn lọ́nà gbogbo ni.

MOA sọ fun àwọn ọ̀bàyéjẹ́ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn alátakò ẹgbẹ́ wọn, pé, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kìíní oṣù Ṣẹrẹ, ẹgbàá ọdún ó lé márun dín lọ́gbọ̀n, tí a wà yí, wọ́n á rí ìbínú Olódùmarè, nítorí iṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń ṣe àtakò fún. 

Nítorí ìdí èyí, àwọn alátakò náà ma rí ìbínú Ọlọ́run gidi.

Gbogbo àwa ọmọ Aládé gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ní ìṣẹ́jú kékeré tó kù yìí; ká má kọsẹ̀, ká má darapọ̀ mọ́ àwọn alátakò; nítorí àtúnbọ̀tán àwọn alátakò ìran kò lè dára. Olódùmarè máa nkẹ̀yìn sí wọn ni.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal