Ẹni tí awífún, Ọba jẹ́ ó gbọ́. Màmá wa, Olóyè ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ti sọ fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) wípé nkan tó nbọ̀, kò ní ṣeé wò tán, nítorí ìwà ìkà àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà lórí ilẹ̀ Yorùbá, ìdí nìyí tí a fi gbọ́dọ̀ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba adelé wa.
Ìwé ìròyìn kan lórí ayélujára ló gbé jáde bí làwọn Hausa ṣe dojú ìjà kọ agbègbè àwọn ọmọ Yorùbá n’ìlú Kàdúná ní ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, látàrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ọmọ Hausa pé ó fẹ́ jalè ní’lé ọmọ Yorùbá, wọ́n sí fàá lè àwọn Hausa ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, nínà tí àwọn yẹ̀n nàá já sí ikú.
Èyí ló mú àwọn Hausa yìí dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n sì ba dúkìá wọn jẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé ẹ̀mí àwọn Yorùbá yìí ṣì wà nínú ewu.
Àtunbọ̀tán ìjẹgàba apanimáyọdà nàìjíríà yìí kò dára rárá. Bíkòṣe ti ìjẹgàba àti ìwà ìkà agbésùnmọ̀mí nàìjíríà pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọmọ àlè Yorùbá tí wọn tà ìran wọn fún Hausa àti Fúlàní, nítorí ohun tí wọn yóò jẹ, irú ìṣẹ̀lẹ̀ yí kò lè ṣẹlẹ̀.
Ní àfikún, nígbàtí màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla gba àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá tó wà ní òkè Ọ̀ya níyànjú láti padà sílé, wọ́n kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ naa. Ó dé’lẹ̀ tán báyìí, wọn ò mọ ọ̀nà àbáyọ.
Òmìnira ilẹ̀ Yorùbá kúrò nínú ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà ti hàn kedere sí àwọn ọmọ Hausa àti Fúlàní pẹ̀lú ẹ̀rí tó kárí ayé tó sì dájú, nígbàtí àwọn ọmọ alè àgbààyà yí ri pé ó ti bọ́ sórí, wọ́n bá parapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá ìran Yorùbá, ìyẹn àwọn Fúlàní láti dojú ìjà kọ ìmúṣẹ ìṣèjọba wa. Yorùbá ti lọ! Èyí ló fa ìkanra tí wọ́n ń ṣe sí àwọn ọmọ Yorùbá tó wà ní òkè ọya.
Olódùmarè ti lo màmá wa MOA láti parí iṣẹ́ òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, nígbàtí a ti búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́.
Ohun tí Olúwa ti ṣe ni òmìnira Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D. R.Y) kò sí ẹnikẹ́ni tó leè yíi padà láéláé.