Láìsí ìmọ́tótó agbègbè àti àyíká wa, nílé, lóko, lọ́nà ìrìn-àjò, kò sí bí a ṣe máa káwọ́ àrùn tàbí àìsàn.
Èyí ló fi dá’ni lójú pé, orílẹ̀-èdè D.R.Y kò ní fi àyè gba ẹnikẹ́ni láti hu ìwà ọ̀bùn tàbí aláìbìkítà fún agbègbè àti àyíká wa ní orílẹ̀-èdè wa yí.
Ìjọba D.R.Y ní ètò tí ó jẹ́ pé ìdọ̀tí, bí ó ti wù kó kéré mọ, kò ní rí ibi fi ṣe ibùjóko ni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).
Ẹ jẹ́ kí ìdọ̀tí jìnà sí wà, kí ó sì jìnà sí gbogbo àwùjọ wa káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. Orílẹ̀-Èdè D.R.Y kò fi àyè sílẹ̀ fún ìdọ̀tí kankan – fún ààbò ara wa ni.
Yàtọ̀ sí èyí, àyíká tí ó dùn-ún-wò, tí ó sì mọ́ tónítóní, máa njẹ́ ìwúrí fún èèyàn láti ro èrò rere fún ìgbélékè ara wa àti ti orílẹ̀-èdè wa. Ìmọ̀tótó borí àrùn.