Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nsọ fún wa pé ọrọ̀ tí ó wà ní ibi tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, kí àwa Yorùbá ti D.R.Y ó tó jáde níbẹ̀, tó kí ẹnikẹ́ni ó máṣe tòṣì. Ìwà-ìkà àti ìmúnisìn ni ó nṣe Nàìjíríà tí ayé fi le koko mọ́ ará-ìlú wọn, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé àwa ti kúrò láarin wọn ní tiwa.
A rí ẹ̀rí tó dájú nípa ọ̀rọ̀ tí Màmá wa sọ yí, nínú ìwé bònkẹ́lẹ́ kan nípa Nigeria èyí tí ó wáyé ní ọjọ́ kọ́kànlélógún oṣù èbìbí, ẹgbàá ọdún ó-dín-márundínlọ́gbọ̀n, nígbàtí ológun Gowon ṣì jẹ́ olórí-ìjọba Nàìjíríà.
Nínú ìwé bònkẹ́lẹ́ yí ni a ti rí pé láarin ẹgbàá-ọdún ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n àtí ẹgbàá ọdún ó dín márundínlọ́gbọ̀n, òjìlélúgbá mílíọ́nù owó dọ́là ni Nàìjíríà yá Ilé-Ìfowópamọ́ Àgbáyé! (World Bank). Ní àkókò yí náà, ọgọ́fà mílíọ́nù dọ́là ni Nàìjíríà yá Àjọ Ìyánilówó Àgbáyé! (IMF).
Èyí túmọ̀ sí pé, ní àgbáyé yí, Nàìjíríà ti fi ìgbà kan yá àwọn ayánilówó, ní owó! À bẹ́ò rí! Ẹni tó nyánilówó fún’ra rẹ̀ pàápàá nyáwó lọ́wọ́ Nàìjíríà! Ìwà aríremáṣe wọn ló jẹ́ kí ojú wọn ó túbọ̀ wọ owó náà, tí ó fi dií pé wọ́n nsọpé kòsówó, kòwóso! Ṣùgbọ́n àpò àwọn olóṣèlú nkún si!
Ní àkókò kan náà yí, ogún mílíọ̀nù owó dọ́là ni Nàìjíríà ná fún Afríkà, nípàtàkì jùlọ, àwọn orílẹ̀-èdè ìwọ̀-oòrùn Áfrikà, àti Àjọ Ìṣọ̀kan Áfríkà (Organisation of African Unity, OAU, èyí tí a mọ̀ sí African Union, AU, lóni). Bẹ́ẹ̀ náà ni Nàìjíríà náwó fún Ilé-Ìfowópamọ́ Ìdàgbàsókè Áfríkà (African Development Bank).
Gbogbo ìgbà tí Nàìjíríà nyánilówó fúnnilówó káàkiri àgbáyé yi, ọmọ Nàìjíríà tí ò lowó tí kò dẹ̀ tálíkà, kò rí tó ọ̀ọ́dúnrún dọ́là gbà lọ́dún o!
Bẹ́ẹ̀ ni Nàìjíríà fún Ilé-Ìfowópamọ́ fún Ìdàgbàsókè àwọn orílẹ̀-èdè Caribbea (Caribbean Development Bank) ní mílíọ̀nù méjì-àbọ̀ dọ́là kí Gowon ó tó kúrò lórí oyè! Pẹ̀lú gbogbo èyí, àwọn tó le kúrò lórí oyè ní ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án láti le kúrò lórí oyè o! Èyí tí ó túmọ̀ sí pé pẹ̀lú gbogbo èyí tí Nàìjíríà nṣe bàbá-olówó káàkiri àgbáyé nígbà náà l’ọhún, ilé wọn kò rọgbọ!
Àwa dúpẹ́ pé, ọjọ́ ológo ni Ọjọ́ náa l’ọhún, ní ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún tí a jáde kúrò nínú ìlú aríremáṣe ọ̀ún, tí a sì ti wá ní ìjọba tiwa báyi, gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdùn ó lé mẹ́rinlélógún, ṣùgbọ́n ojú méjèèjì ni D.R.Y fi máa tọ́jú ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P). Kò sí àyè fún ohunkóhun yàtọ̀ sí ìrọ̀rùn fún I.Y.P ti D.R.Y.
Ẹ jẹ́ kí á gbárùkù ti Ìjọba Adelé wa, lábẹ́ àkóso Olórí Adelé, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, kí Èdùmàrè nínú àánú rẹ̀, ó bá wa ṣí ìdí ajẹgàba Nàìjíríà kúrò ní ilẹ̀ wa, láìpẹ́ àti láìjìnà.