A rí ìròyìn kan lórí ẹ̀rọ ayélujára nípa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Gani Adamu, tí wọ́n pé ní Àrẹ ọ̀nà kakanfò ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Ọkùnrin náa ní inú òun kò dun sí bí ìlú ṣe dà, àti bí epo bẹntiróólù ṣe wọ́n gógó ní ìlú, tí eku kò leè ké bí eku, tí ẹyẹ kò leè ké bí ẹyẹ, àti bí ọmọ ènìyàn kò sí leè fọhùn bí ọmọ ènìyàn ní àrin ìlú mọ́, ti ìnira sì bá gbogbo ènìyàn.
A nfi àsìkò yí ran oníròyìn yìí àti àgbáyé létí pe, kò sí ọba tàbí olóyè kankan ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí màmá wa MOA sọ fún wa wípé àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kàn ń lo àwọn tí wọ́n pè ní ọba wọ̀nyí láti jẹ́ aṣojú ọmọ ìta ni àti láti máa tan ará ìlú jẹ.
Àwọn ọmọ ìta tí wọ́n kò ìlẹ̀kẹ̀ sí lọ́rùn, tí wọ́n dé adé sí lórí lásán ni wọ́n, láti leè máa lò wọ́n fún iṣẹ́ ibi, sebí ẹ mọ̀ pé ọkùnrin tó ń sọ̀rọ̀ yìí náà ara àwọn ọmọ ìta tí wọ́n ń lò ni òun náà.
Orilẹ́ èdè Yorùbá kò sí ní fi àyè gba ìwà ọmọ ìta, nítorí ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ará ìlú àwọn ìkà agbèsùnmọ̀mí Naijiria mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ti sọ òtítọ́ fún wa pé D.R.Y kò ní nkan ṣe pẹ̀lú ọba rárá, nígbàtí a sì bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nípa ìbúra wọlé fún bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ gẹ́gẹ́bí olórí Adelé wá ní wọ́n tí pàṣẹ pe, kí gbogbo ẹgbẹ́ tàbí ìkórajọpọ̀ di títúká lọ́gán, àṣẹ yìí sí bá àwọn ọba ati ìjòyè wi, fún ìdí èyí, kò sì Àrẹ Ònà kakanfò ní orílẹ̀ édè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá mọ́, àti pé Gani Adamu kò ní àṣẹ láti ṣe agbẹnusọ fún ọmọ Yorùbá rárá.
Nípa ọ̀wọ́ngógó owó epo bẹntiróòlù, màmá wa ti sọ fún wa pé ní kété tí a bá ti lé àwọn àjẹgaba agbésùnmọ̀mí Naijiria kúrò lórí ilẹ̀ wa láì pẹ́ yìí, owó epo bẹntiróòlù, oúnjẹ àti gbogbo àwọn nkan t’ókù á wálẹ̀ a ó sì bọ́ sínú ìrọ̀rùn, nitori àwọn ìjọba Adelé wá nṣiṣẹ́ takun takun láti mú ayé rọrùn fún gbogbo ọmọ Yorùbá.