ÈDÈ YORÙBÁ

Kíni a npè ní èdè? Èdè jẹ́ oùn. Bẹ́ẹ̀ náà ni èdè jẹ́ Ìsọ̀rọ̀ sí, tàbí iṣesọ̀rọ̀.

Èdè túmọ̀ sí ohun tí a fi ngbé nkan t’ó wà nínú ẹ̀mí wa, jáde sí’ta, kí ẹni tí ó bá gbọ́ọ, kí ohùn náà tí a sọ já’de yẹn, kí ó le di Ẹ̀mí nínú òun náà: nítorí èyí, èdè ni oùn tí ó njá’de l’ati inú ẹ̀mí mi wá – tí ó ngba ẹnu mi já’de, sí etí ẹni tí mo mbá sọ̀rọ̀; tí ó bá ti wá wọ’nú etí tirẹ̀ lọ, ó yẹ kó wá di Ẹ̀mí nínú òun náà: èyí tí ó tú’mọ̀ sí pé, ẹ̀mí mi (orísun mi) ti bá ẹ̀mí ẹni t’ọ̀ún (orísun rẹ̀) sọ̀rọ̀.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

L’oótọ́ àti l’ododo, ọ̀pọ̀ ni ó máa ns’ọ̀rọ̀ tí wọn ò sọọ́ l’ati inú ẹ̀mí wọn wá, tàbí tí wọ́n ngbọ́ ọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí wọn ò fi ẹ̀mí wọn gbọ. Irúfẹ́ èyí kò dára.

Nítorí náà, èdè jẹ́ ohun ìbánis’ọ̀rọ̀, l’ati inú ẹ̀mí ẹni tí ó ns’ọ̀rọ̀, sí ẹ̀mí ẹni tí a ns’ọ̀rọ̀ náà sí.

Ẹ̀mí ni òye ti nyé’ni, ẹ̀mí sì ni a ti nmú ọgbọ́n já’de.

Èdè Yorùbá wá ṣe pàtàkì nínú àwọn èdè tí ó wà l’ayé, nítorí èdè Yorùbá jẹ́ èyí tí ó jinlẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀! Èdè Yorùbá, láti inú Ẹ̀mí Olódùmarè ni ó ti wá, nítorí oríṣàdá ni Ìran ọmọ Yorùbá jẹ́.

Ẹ̀mí Yorùbá níláti wà nínú ènìyàn, kí a tó lè sọ Yorùbá dáadáa; nítorí náà, kìí ṣe-é pé kí ọmọ ẹ̀yà míràn ó kọ́ èdè wa, ìyẹn kọ́ ló túmọ̀ sí pé ó sọ èdè wa: kò sí ẹni tí ó lè sọ èdè kankan láì ní ẹ̀mí Ìran t’ó ni èdè náà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó kàn sọọ́ lórí ahọ́n ni, kò sọọ́ láti inú ẹ̀mí. Sís’ọ̀rọ̀ láti inú ẹ̀mí ṣe pàtàkì: kò sí ẹni tí ó le sọ̀rọ̀ láti inú ẹ̀mí tí kìí bá nṣe ọmọ Ìran t’ó ni Èdè náà nínú ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀!

Nítorí ìdí èyí, èdè jẹ́ ohun Ẹ̀mí, ẹni tí kìí ṣe Ìran náà, kò lè sọ Èdè Ìran yẹn láti inú ẹ̀mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣọọ́ lórí ahọ́n.

Èyí ni ó wá d’ifá fún bí Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe sọ pé, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), Èdè Yorùbá ni Èdè-Ìbánis’ọ̀rọ̀ tí Ìjọba àti Òfin Ilẹ̀ wa pọn-dan-dan fún ohunkóhun, àti nínú ohun gbogbo tí a bá nṣe gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè, èyíinì ni pé Èdè Yorùbá ni Èdè Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).

L’ẹhìn èdè Yorùbá, kò tún sí èdè míràn, láyé, tí a máa lò gẹ́gẹ́bi Orílẹ̀-Èdè, yálà ní ilé-iṣẹ́ ìjọba ni o, tàbí ní ilé-iṣẹ́ àdáni gbogbo, tàbí ní ilé-ìwé gbogbo – yálà ní kíkọ sí’lẹ̀ tàbí ní sísọ l’ẹnu.

Ẹni tí kò bá ti lè sọ èdè Yorùbá, kí ẹni náà ó gba ògbufọ̀ tí ó máa máa lò ní ibi gbogbo tí ó bá nlọ, nítorí, ìbáà ṣe iṣẹ́ ìjọba, ìbáà ṣe ti aládani, ọ̀ràn dídá ni fún ẹnikẹ́ni l’ati máa lo èdè míràn yàtọ̀ sí Èdè Yorùbá.

Eléyi tún wá ṣè pàtàkì jùlọ fún wa, nítorí, nípa èdè wa ni Ẹ̀mí àti Ìṣẹ̀dá tí Olódùmarè dá Ìran Yorùbá, ṣe máa ní àyè l’ati wá sí Ìmúṣẹ ní Ilẹ̀ Yorùbá, àti káàkiri àgbáyé.

Ara ìdí tí Ìran Yorùbá ṣe wà nínú ìgbèkùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún báyi, tí kìí bá nṣe nísiìyí tí Olódùmarè ti gbà wá s’ilẹ̀, ni pé Èdè wa wà nínú Ìgbèkùn. Ìran-kí’ran tí Èdè wọn bá ti wà nínú ìgbèkùn, ìran náà ti wà nínú ìgbèkùn nìyẹn! Nítorí, nípasẹ̀ èdè ni ìjénìyàn Ìran ṣe máa nwá sí ìmúṣẹ!

Kò sí Ìran náà ní Ayé yí tí ó le di ohun tí Ọlọ́rùn fẹ́ kí wọ́n dà láyé tí wọn ò bá rí Èdè wọn sọ!

Nínú èdè wa ni ohun ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ wa wà! Láìsí èdè wa, a ò lè ṣe àwárí ara wa gẹ́gẹ́bí Ìran. Ṣùgbọ́n nísiìyí tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí lo Èdè wa, a máa ṣe àwári Ìran wa ní Kíákíá!

Èdè wa ni àwọn ọmọ wa, láti ẹnu ọmú, níláti máa gbọ́; nígbàtí ó bá sì tó àsìkò fún wọn láti fọ’hùn, èdè wa nìkan ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èdè tí ó nti ẹnu wọn já’de, bákannáà ni fún àwa òbí wọn.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024

A gbọ́dọ̀ kó ara wa ní ìjánu lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí a kò gbọ́dọ̀ da Ìran Yorùbá nínú ọ̀rọ̀ yí rárá: nítorí náà, kìí ṣe pé kí a wá rí oníbarà wa tí kìí ṣe ìran Yorùbá, kí a wá máa ba dú’nádú’rà ní èdè míràn tí kìí ṣe Èdè Yorùbá. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí kò bá lè sọ Yorùbá, tí kò dẹ̀ fẹ́ gba Ogbufọ̀, kí ó wá ibòmíràn lọ, ilẹ̀ Yorùbá kò fẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀.

L’oótọ́, ìyá wa, MOA, sọ pé, Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ díẹ̀ máa wa, (wọn ò pọ̀, rárá), tí ó máa jẹ́ Ilé-Ẹ̀kọ́ Èdè – ìwọ̀nyí wà fún àwọn tí ó bá ní èdè kan tàbí òmíràn tí wọ́n ní’fẹ sí l’ati kọ́, ṣùgbọ́n, èdè Yorùbá náà ni wọ́n á fi kọ́ wọn níbẹ̀, ó dẹ̀ ní ìwọ̀n’ba péréte irúfẹ́ wọn tí Ìjọba Yorùbá máa fún ní aṣẹ – ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gbogbogbò láti alákọbẹ̀rẹ̀ dé fásitì o! – àwọn yẹn, Èdè Yorùbá NÌKAN ni ẹnikẹ́ni lè sọ ní’bẹ̀.

Tí àjèjì bá dá ilé-iṣẹ́ sí’lẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, gbogbo ohun tí wọ́n nṣe nínú àti ní’ta ilé-iṣẹ́ náà, gbọ́dọ̀ jẹ́ ní Èdè Yorùbá, nigbà gbogbo, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ilé-iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ti dá ọ̀ràn gidi lábẹ́ Òfin wa.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ̀ fi èdè míràn, yàtọ̀ sí Èdè Yorùbá, kọ́ ẹnikẹ́ni ní àwọn ilé-ìwé, ìbáà ṣe ilé-ìwé ìjọba, ìbáà ṣe ti aládani, ìbáà ṣe ọmọ Yorùbá ni akẹ́kọ́ náà, tàbí kìí ṣe ọmọ Yorùbá, irúfẹ́ olùkọ́ni bẹ́ẹ̀ ti dá ọ̀ràn tí ó l’agbára l’abẹ́ Òfin Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.

Èdè Yorùbá ni Ẹ̀mí Ọmọ Yorùbá; èdè Yorùbá ni Ọjọ́-Iwájú ìran Yorùbá. Èdè Yorùbá ni Èdè kanṣoṣo tí ilẹ̀ Abínibí Yorùbá gbọ́ – ilẹ̀ Yorùbá kò gbọ́ èdè míràn yàtọ̀ sí Yorùbá. Bí a bá ṣe nsọ Èdè Yorùbá ní Orí-Ilẹ̀  Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni Ilẹ̀ Yorùbá yíò máa gbọ́ ti’wa sí Rere, tí ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá á dẹ̀ máa gbọ́ ti’wa; ṣíṣe èyí ni Ẹlẹ́da Ìran Yorùbá, Olódùmarè, yíò máa dún’nú sí wa ní ohun gbogbo.

Èdè wa tí àwọn amúnisìn gbà lẹ́nu wa, níjọ́un, lọ́hun, ni wọ́n fi kó wa lẹ́rú, tí ó fi jẹ́ pé àti àwa fún’ra wa, àtí àwọn ọmọ wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wa bákannáà, a ò le sọ Èdè wa bí ó ṣe yẹ kí á sọọ́. Ìyẹn ni wọ́n fi kó wa lẹ́rú, ṣùgbọ́n ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé èdè wa gan-an gan ni Ìdánimọ̀ wa. Ìlú tí kò bá sọ èdè abínibí wọn, kò le gbé’rí.

Fún ìdí èyí, àwa ò fi èdè wa ṣe’ré ní Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y. Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, MOA, ṣe fi kọ́ wa, Èdè ni a fi ndá Orílẹ̀-Èdè mọ̀.