Alágbára mà ni Ọlọ́run Elédùmarè, ìròyìn kan ló tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní ìlú àwọn agbésùnmọ̀mí Naijiria nípa ọmọ ọdún kan tí àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà rí nínú igbó Sambisa ti ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Ọlọ́run nípè ti jẹrà lati ìdodo dé ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣugbọ́n gbogbo igbáàyà rẹ̀ lo ṣe rẹ́gí, tí ọmọdé yi sì ń rí ǹkan mu nínú ọyàn ìyá rẹ̀.

Tí àwọn ọmọ ogun apanilẹ́kún jayé Naijiria lérò pé, àwọn Jàndùkú kan ló fẹ́ fi ọmọ náà ṣe àkóbá fún wọn. Ṣebí, bí ìjọba agbésùnmọ̀mí ṣe ń fi ikú dá àwọn ọmọ Yorùbá tó ń ṣe iṣẹ́ ológun ní ìlú nàà lóró nì yẹn.

Ṣé tí ìlú wọn bá dára ni, kíni ọmọdé yii fẹ́ ma wá nínú igbó aginjù, láì ṣe ẹranko. Ìlú afi’pá jẹ gàba Nàìjíríà jẹ́ ìlú tí kò láàbò rárá, tí kò sì ní ẹran ènìyàn lára.

Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) kò ní fi àyè gba irú ìwà àìbìkítà bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ wa rárá.

Ìròyìn náà jẹ́ ohun tí ó fi agbára ọlọ́run han, nínú ayé ọmọdé náà. Ọ̀rọ̀ pé ìbàjẹ́ ènìyàn kò dá’ṣẹ́ olúwa dúró, ló wá já sí, ìbàjẹ́ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kò dá àánú olúwa lórí ọmọ náà dúró.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 02/09/2024

Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ bí ìbàjẹ́ ìlú awáyémáserere nàìjíríà kò ṣe dá ìkéde òmìnira Democratic Republic of the Yorùbá ((D.R.Y) dúró l’ọ́jọ́ náà lọ́hùn-ún nìyẹn, ọjọ́ ológo, ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún; bẹ́ẹ̀ náà ni ìbàjẹ́ àti gbogbo ìhàlẹ̀ wọ́n, kò dá Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni D.R.Y dúró, pẹ̀lú ìbúra-wọlé fún olórí-ìjọba-adelé wa, Bàbá wá, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ọjọ́ ògo àwa ọmọ Yorùbá, tí a ní ìjọba tiwa níkàlẹ̀.

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìránṣẹ́-Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa ń sọ, Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá Yorùbá, ló ń rin ìrìn, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ náà; òun ló ń ṣáájú, tí Màmá wa àti àwa náà ń tẹ̀lée; kí gbogbo ìjọ ènìyàn yí le mọ̀ pé Olúwa kìí fi idà tàbí ọ̀kọ̀ gba’ni là; nítorí, tí Olúwa ni ogun náà, Ó sì ti fa gbogbo àwọn ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́.