Ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, tí ó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba láìní ẹ̀tọ́ kankan lábẹ́ òfin ní àgbáyé láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí ó sì jẹ́ ìwà ọ̀daràn, ìwà ìkọlu-orílẹ̀-èdè-míràn èyí tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè aṣejọba-ara-ẹni ti ara rẹ̀.
Ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjírìà jẹ́ ìlú tí ó ń jí ohun tí wọ́n bá ti gbọ́ pé Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá sọ nípa ọ̀rọ̀ ṣíṣe-ìlú tàbí ìgbésẹ̀ tí ó wà nínú ètò fún D.R.Y, wọ́n máa ń gbé irú ìgbésẹ̀ tí ó jọ mọ́ èyí tí wọ́n gbọ́ pé D.R.Y fẹ́ ṣe; bẹ́ẹ̀ sì ni , wọn ò mọ kúlẹ̀-kúlẹ̀ tàbí àṣepé ìgbésẹ̀ náà!
Èyí kò sì tu irun kankan lára dídádúró tí orílẹ̀-èdè wa ti dádúró láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lélógún.
Kò sí ohun tó leè yíi padà láéláé, a ti jáde kúrò nínú aríremáse nàìjíríà, a kìí ṣe ara ajẹgàba nàìjíríà mọ́. Yálà apanilẹ́kún jayé nàìjíríà fẹ́ tàbí ó kọ̀, ó máa kúrò lórí ilẹ̀ wa láìpẹ́.
Èyí tí a tún gbọ́ tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà fẹ́ ṣe báyìí ni wípé, kí àwọn àjòjì tí ó wà ní ìlú wọn ó máa gba káàdì ìdánimọ̀ ìlú wọn ọ̀hún.
Èyí dà bí ìgbà tí ẹni tí kò mọ ìdáhún sí ìbéèrè bá ń jí iṣẹ́ ẹlòmíràn wò tí ó sì ń kọ ìdáhùn ti ẹlòmíràn sílẹ̀ láì mọ ìbéèrè tí ó fa ìdáhùn ọ̀hún pàápàá.
Ṣebí ní ìgbà díẹ̀ s’ẹyìn báyi, ní Màmá wa sọ pé a máa ní Ìdánimọ̀ tí a pè ní “Indigenous Yoruba Identification Number” (ÌYÌN), àti èyí tí a pè ní “Citizen Identification Number” (CIN), tí aláìní-làákàyè nàìjíríà kò mọ ìdí tàbí ìtumọ̀ ìdánimọ̀ wọ̀nyí; tí wọ́n kàn ṣáà gbọ léréfe, tí àwọn náà ń sọ pé kí àwọn àjòjì tí ó wà láàárín wọn máa ní ìdánimọ̀ Nàìjíríà. Wọn ò kúkú mọ ohun tó wà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba D.R.Y.
Agbésùnmọ̀mí nàìjíríà o rò pé o lè máa ṣe ohun tí ẹ bá ti ń gbọ́ lẹ́nu màmá wa,ohun tí ẹ bá gbọ́ lẹ́nu MOA kò tó ìdá kan ohun tí wọ́n ò sọ síta. Kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y); o ń dá ọ̀ràn lábẹ́ òfin àgbáyé ni pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ gàba lórí ilẹ̀ wa, o sì máa kábàámọ̀ láìpẹ́ jọjọ.