Ìròyìn kan t’ó tẹ̀ wá l’ọwọ́ sọ wípé, ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti ngbìn ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ erè oko tí a rò wípé nàìjíríà l’ọhún ni wọ́n ti nko wọn wá sí ilẹ̀ wa! À b’ẹò ri!
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XNí nkan bí àádọ́ta ọdún s’ẹhìn, ìlú nàìjíríà nígbànáà kó ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ají’lè wọ’lé l’ati òkèèrè, tí wọn kò sì ṣe àyẹ̀wò fínífíní l’orí àwọn ajílẹ̀ wọ̀nyí!
Àwọn ají’lẹ̀ tí kò dára fún ilẹ̀ ni; tí ó sì ba ilẹ̀ jẹ́, l’ọpọ̀l’ọpọ̀! Nígbànáà l’ọhún, wọ́n rò wípé àwọn fi nṣe wá ni, wọn ò kó àjílẹ̀ yí wá sí ọ̀dọ̀ wa ní’bí ṣùgbọ́n wọ́n ko lọ sí ib’òmíràn.
Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, ìpínlẹ̀ Bẹ́núè ní Nàìjíríà jẹ́ ibi tí wọ́n ti máa ndá’ko l’ọpọ̀l’ọpọ̀, tí ilẹ̀ wọn sì dárá ní’gbà láíláí. Wọ́n ti lẹ̀ máa npè wọ́n ní “Apẹ̀rẹ̀ Onjẹ” ìlú Nàìjíríà.
Èèmọ̀! Àwọn Ọ̀dọ́ Yorùbá Mbẹ̀bẹ̀ Fún Owó Ní’gboro Èkó
Gẹ́gẹ́bí apẹrẹ, wọ́n máa ngbin ọpọ̀l’ọpọ̀ iṣu – èyí tí àwọn fún’ra wọn máa jẹ, tí wọ́n á sì tún tà, bákannáà, nínú ọjà tiwọn, bẹ́ẹ̀ náà ní wọ́n tún ní àwọn tí wọ́n ntà lọ sí àwọn agbègbè tí ó yí wọn ká; ní ọ̀nà kẹ́ta ẹ̀wẹ̀, wọ́n ni iṣu tí wọ́n tún ntà sí ọ̀nà jínjìn réré; oríṣi ọ̀gbẹ̀ iṣu mẹ́ta, ní’pele ní’pele yí ni wọ́n ní! Ṣùgbọ́n a gbọ́ wípé nkan ti yípadà o!
Àwọn ajílẹ̀ tí wọ́n rò wípé wọ́n ṣe’kà fún wa nígbànáà, tí wọ́n nko lọ sí apá ib’òmíràn, tí ó sì jẹ́ èyí tí ó mba ilẹ̀ jẹ́; eléyi ti ba ilẹ̀ jẹ́ l’ọpọ̀l’ọpọ̀ ní àwọn ibi tí wọ́n ko lọ ní’gbànáà, tí ó fi jẹ́ wípé, irúfẹ́ ìpín’lẹ̀ Bẹ́núè ní Nàìjíríà yẹn, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, ọ̀gbìn iṣu kò rí bí o ṣe rí tẹ́’lẹ̀ mọ́.
A gbọ́ wípé, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ohun ọ̀gbìn tí wọ́n ntà fún wa ní ilẹ̀ Yorùbá, l’oní, tí a rò wípé òkè l’ọhún, tàbí wípé ilẹ̀ Haúsá ni ó ti nwá, kò rí bẹ́ẹ̀ o!
Ayédatiwa, Kúrò L’orí Àlééfà Ọmọ Yorùbá
L’ara ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti ngbìn-í, tí wọ́n á sì ko wá fún wa, tí àwọn kan nínú ọmọ Yorùbá á máa sọ wípé, l’at’òkè ní Nàìjíríà ni wọ́n ti nkó onjẹ wá fún wa! Eléyi kò rí bí ẹ ṣe ròó o!
Bákannáà ni ìròyìn tẹ̀ wá l’ọwọ́ wípé, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn ohun tí àwọn òyínbó tí wọ́n nfẹ́ ìṣe’kúpa aláwọ̀dúdú, tí wọ́n ndá’bá àti kó wá sí ọ̀dọ̀ wa l’oní, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, àwọn irú’gbìn ayédèrú tí a mú ìròyìn wá báa yín nípa rẹ̀, ní àìpẹ́ yí, ó pẹ́ tí wọ́n ti nkó irúfẹ́ rẹ̀ lọ sí òkè ọya l’ọhún!
Ara ohun tí ó ṣe okùn’fà wípé kí ilẹ̀ wọn má dára tó bí ó ṣe yẹ, l’okè l’ọhún, náà nìyẹn!
Kíni ìtú’mọ̀ gbogbo eléyi fún wa? Èkíní, a dúpẹ́ l’ọwọ́ Elédùmarè wípé, kò sí nkan t’ó ṣe ilẹ̀ tiwa o!
A kò sí gbọ́dọ̀ gba irú’gbìn k’irú’gbìn kankan l’ọdọ̀ ẹnik’ẹni, tàbí ohunk’ohun t’ó máa ba ilẹ̀ wa jẹ́, tàbí ṣe àìsan sí wa l’ara.
Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Ṣe Òfin Oní’lé-Gbé’lé Ní Èkìti!
Ṣe bí wọ́n nrò wípé àwọn dá’jú wa nígbànáà l’ọhún ni! Kìkìdá kí á lé ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kúrò l’órí ilẹ̀ wa, báyi, l’ó kù; gbogbo ọ̀rọ̀ wípé ilẹ̀ Háúsá ni wọ́n ti nkó onjẹ wá fún wa yẹn, Háusá kankan kọ́ l’o nbọ́ wa o! K’a má ri!
Ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti ngbìn ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ohun tí a njẹ! L’ati ayébáyé ni Yorùbá ti ní ilẹ̀ tí ó l’ọrá, nípa èyí tí onjẹ, àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù ti wà fún wa!