Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá l’ó sọ bẹ́ẹ̀.
Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kan l’ó sọ wípé, Àpapọ̀ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, sọ fún ẹ, ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa, tí o pe ara rẹ ní gómìnà ìpínlẹ̀ Ondó; oò kìí ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Ondó o!
Ìwọ l’o pe’ra ẹ bẹ́ẹ̀! Lucky Orímisàn Ayédatiwa, kúrò l’orí àlééfà ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá!
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XÓ ti wá d’ojú ẹ̀, báyi o! O nṣẹ̀ sí òfin àti agbára ìṣè’jọba-ara-ẹni ti Orílẹ̀-Èdè Olómínira Tiwantiwa ti Yorùbá; bẹ́ẹ̀ náà ni o nṣẹ̀ sí òfin àgbáyé!
Ibi t’o jóko sí yẹn, ní Àkúrẹ́, ti kúrò nínú Nàìjíríà; ó ti di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; orílẹ̀-èdè tí ó yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí ìwọ f’ara mọ́; o f’ara mọ́ Nàìjíríà; kò burú; máa bá nàìjíríà ẹ lọ; kúrò l’orí àlééfà ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá! À b’oò l’etí ni? Yorùbá kò sí l’ara nàìjíríà mọ́!
Ọ̀gá ẹ, t’ó ṣáájú ẹ, Rotìmí Akérédolú, ti gba lẹ́tà l’ati oṣù kéjìlá ọdún 2022, ìwọ náà dẹ̀ wà ní’bẹ̀ nígbànáà; ẹ jìjọ gba lẹ́tà náà ni; nítorí ìwọ ni igbá kéjì ẹ nígbàyẹn; ẹ jìjọ wà l’órí àlééfà ni, nít’orí “joint ticket” l’ẹ lò, l’abẹ́ òfin Nàìjíríà, l’ati jọ dé bẹ̀; nít’orí náà, o mọ ohun tí a nsọ! O ò lè sọ wípé oò mọ̀ọ̀!
Ní ọjọ́ kọ́kàn-dín-l’ọgbọ̀n, oṣù kéjìlá, ọdún 2022, ni ẹ ti gba ìwé, tí ọmọ Yorùbá, l’abẹ́ àsíá ÒMÌNIRA YORÙBÁ 2022, kọ sí yín, wípé, a dúró l’orí Ìkéde Òmìnira tí a ti ṣe l’ati ogúnjọ́, oṣù kọ́kànlá, ọdún 2022, wípé ilẹ̀ Yorùbá, àti ọmọ Yorùbá ti já’de kúrò nínú nàìjíríà; a kìí ṣe ara nàìjíríà mọ́!
Ká Ìròyìn: Àgbà’yà, Bísí Àkàndé Gba Ipò Pro-Chancelor (Al’aga Ìgbìmọ̀) Fásítì Ìbàdàn
Ẹ kúrò l’orí ilẹ̀ wa! A ò sọ wípé ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa; a ò sọ wípé oò kìí ṣe ọmọ Yorùbá o! A mọ̀ ẹ́ sí ọmọ Yorùbá; a mọ̀ ẹ́ sí ọmọ ìpínlẹ̀ Ondó; ṣùgbọ́n, ìpínlẹ̀ Ondó ti wá yàtọ̀, nísiìyí, sí ìpínlẹ̀ Ondó tí ó wà tẹ́’lẹ̀! O mọ òfin!
Ìpínlẹ̀ Ondó tí ó wà, tẹ́’lẹ̀, nígbàtí ìwọ àti Akérédolú wà l’orí àlééfà, kí ó tó di ogún’jọ́ oṣù kọ́kànlá, ọdún 2022, jẹ́ ìpínlẹ̀ Ondó nínú Nàìjíríà; l’abẹ́ Nàìjíríà ni ìwọ àti Akérédolú fi wọ orí àlééfà ìpínlẹ̀ Ondó; ṣùgbọ́n l’ati ogún’jọ́ oṣù kọ́kànlá ọdún 2022, ìpínlẹ̀ Ondó kò sí l’abẹ́ nàìjíríà mọ́!
Àgàgà, l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin ọdún 2024 yí, a ti ṣe ìbúra-wọ’lé fún olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba – D.R.Y), l’ẹhìn tí a ti ṣe Ìpolongo Ìṣè’jọba-Ara-Ẹni (Sovereignty) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ní ọjọ́ náà, bákannáà; èyí tú’mọ̀ sí wípé, l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, ọdún yí (2024), ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa, a nsọ fún ẹ wípé, Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y, ti wà l’orí àlééfà, ṣùgbọ́n ìwọ Lucky Orímisàn Ayédatiwa, óò fẹ́ kúrò l’orí ìjóko-àga àlééfà náà ní ìpínlẹ̀ Ondó.
Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Tún-tún Ní Àgbáyé, Olómìnira Tiwantiwa 55th Ní Áfíríkà
O lè máa béèrè wípé tani gómìnà ìpínlẹ̀ Ondó l’abẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Ìwọ má ṣe wàhálà l’orí ìyẹn.
Tì ẹ ni wípé, kúrò l’orí alééfà ọmọ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ondó, tí o kò bá fẹ́ kan ìdin nínú iyọ̀. A ti sọ, sọ, sọ tó; Lucky Orímisàn Ayédatiwa, JÁ’DE KÚRÒ NÍ Ọ́FÍÌSÌ ÌJỌBA NÍ ALÁGBÀKÁ NÍ ÀKÚRẸ́! – TINUBÚ NKÓ Ẹ ṢI’NÀ NI! YORÚBÁ TI DÁDÚRÓ, PÁTÁPÁTÁ, L’ATI ỌJỌ́ KÉJÌLÁ OṢÙ KẸ́RIN, ỌDÚN YÍ! A nk’ìlọ̀ fún ẹ ni o! Ó ku díẹ̀ t’o máa tẹ́! Àfi k’o tètè já’de kúrò ní Alágbàká; Yorùbá kò sí l’abẹ́ Nàìjíríà mọ́!