Àfojúdi, ìgbéraga àti àìmọ̀kan wà lára ọ̀ràn tí ó bá ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.

Ìgbéraga wọn ló sọ wọ́n di aláfojúdi! Tí wọn ò bá ní ìgbèraga ni, wọn bá má fojúdi ìwé Ìgbàpadà tí ọmọ-Yorùbá kọ sí gbogbo gómìnà wọn tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá, láti ó-lé-ní-ọdún-kan báyi! Ó lé ní ọdún kan, láì fèsì, ó ní nkan tí ó túmọ̀ sí lábẹ́ òfin ní àgbáyé! Kò yé wọn! Ìgbéraga wọn kò jẹ́ kó yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni àfojúdi wọn kò jẹ́ kí wọ́n ronú gbé ìwé náà yẹ̀ wò.

Ìkan tún ti ṣe wọ́n ní ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yí. Màmá Ìran-Yorùbá ni ó ṣí ojú wa si ní àìpẹ́ yí, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, Ìránṣẹ́-Olódùmarè. Wọ́n rán wa létí pé ní ọjọ́ kéjìlá oṣù ọ̀wàrà ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ni ó pé oṣù mẹ́fà, géérégé, tí a ṣe ìbúra-wọlé fún Ìjọba-Adelé wa, lẹ́yìn tí a ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjoba-Ara-Ẹni Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y). Pípé tí ó sì pé oṣù-mẹ́fà yí ní Ìtumọ̀ ohun tí ó já sí Lábẹ́ Òfin.

Ṣé Nàìjíríà máa nfi òfin ṣe’ré ni, ó dáa, ojú wọn á ja!

Agbára Àkọsílẹ̀ lábẹ́ òfin, ṣíṣiṣẹ́ tọ Àkọsílẹ̀ náà, àti lílo ìtúmọ̀ ìgbà àti àkókó ìgbésẹ̀-lábẹ́-òfin, gbogbo ẹ̀ ni ó pẹ̀lú ohun-ìjà, ìjà-Ọgbọ́n tí Olódùmarè ṣe oore rẹ̀ fún wa, nípasẹ̀ Ìyá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítiri-Abíọ́lá.

Ṣebí wọ́n máa nsọ ní ilẹ̀ Yorùbá pé Ọgbọ́n-ju-Agbára lọ ! Òun l’ó nṣẹlẹ̀ yí o! Lẹ́yìn oṣù-mẹ́fà tí ìjọba-Adelé wa ti wà ní’pò, àwọn Nàìjíríà ṣì nkápá sókè lórí ilẹ̀ wa; ìfọ́jú ti kọ lù wọ́n, wọn ò mọ ohun tí ó túmọ̀ sí pé ó ti pé oṣù mẹ́fà. Àwọn àṣìṣe báyì ni wọ́n máa máa ṣe, tí wọ́n á gba ìtìjú jáde kúrò ní ILẸ̀ WA, ìlẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

Ẹni tí ó bá fojú di agbára Olódùmarè, ó tẹ́ tán! Kí ìkẹ́ àti ìgẹ̀ Ọlọ́run kí ó wà títí láí pẹ̀lú Ìránṣẹ̀ Rẹ̀, Ìyá wa, ẹni tí Ọlọ́run yàn.

A kú orí-ire o, àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) pé ó ti pé Oṣù-Mẹ́fà tí a ti ṣe Ìpolongo-Ìṣèjọba-Ara-Ẹni, tí a sì ti ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí Ìjọba-Adelé wa, ní orí-ìlẹ̀ wa! Ó ní ìtumọ̀ l’abẹ́ Òfin!

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá