Nígbà tí Olódùmarè ṣẹ̀dá ìran Yorùbá, Ó fún wa ní èdè kan, àṣà kan, Ó sì dá wa sí orí ilẹ̀ kan. Èyí túmọ̀ sí pé láìsí àní-àní, ọ̀kan ṣoṣo ni wá.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó gbé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde láti dá ìran Yorùbá padà sí orírun wa. Gbogbo ìgbà ni màmá wa MOA máa ń sọ fún wa wípé, kò sí ẹlẹ́yàmẹ̀’yà ní ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan náà ni wá.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a ṣe ara wa lọ́kan.
Kí a má ṣe gba àjèjì láàyè láti ṣe ohunkóhun tó lè fa ìpínyà láàárín ìran Yorùbá, nítorí tí ògiri ò bá la’nu aláǹgbá ò lè wọ’bẹ̀. Kí a sì máa rántí wípé lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.