Nínú ohun gbogbo, ẹ jẹ́ kí a máa bẹ̀rù Ọlọ́run, àwọn tí ìrẹ̀ wọ́n yó tán, tó wá ní kí wọ́n fi kété tú ìfun òun, ni ọ̀rọ̀ àwọn tí a fẹ́ sun jẹ, tí wọ́n wá fi epo para, wọ́n bá lọ jókòó ní ẹ̀yìn ààrò; òun ní ọ̀rọ̀ àwọn agbéraga tí wọ́n pé’ra wọn ní ọba ní ilẹ̀ Yorùbá; àwọn tí ó yẹ kí wọ́n f’orí pamọ́, kí wọ́n sì máa ra’wọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè pé, kí ó dárí àṣìṣe wọn jìn wọ́n, ṣùgbọ́n, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n tún ń dá ọ̀ràn mọ́ ọ̀ràn.

Ìròyìn kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, ni kìí ṣe àjèjì sí wa, ṣùgbọ́n, ó fi hàn kedere pé, wọn kò ní àyípadà ọkàn ju kí wọ́n máa ṣe ibi wọn lọ síwájú sí i. Ó dájú pé, ẹni tí ó bá ti ń bá Ọlọ́run fi iga gbá ‘ga, ìparun rẹ̀ tí wà ní ẹ̀yìn ọrùn rẹ̀.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

 Ọ̀kan lára awon tó ṣì ń pe’ra wọn ní ọba ní ìlú Eko, Adeniyi Ajayi, ni ó yó tán, ó ní pé, kò si ohun tí Ọlọ́run pàápàá le ṣe fun òun lórí ilé àti ilẹ̀ ẹni tí kò ní agbára, tí òun wa ń fi ọwọ́ ọlá gbá lójú, tí ó sì gba ilẹ̀ náà, tí ó tún wó ilé orí rẹ̀, ilẹ̀ tí oní-nkan ti rà láti ọdún mẹ́rin-lé-lógún sẹ́yìn. A ríi nínú àwòrán tí wọn ti da ilé náà wó lulẹ̀. 

 Ìròyìn náà sọ pé obìnrin tí ó  ni  ilẹ̀ yí ti lé ní àádọ́rin-ọdún lọ́jọ́ orí. Ẹ̀yin kan wá ń fi owó b’ayé jẹ́, ẹ kì í kúkú ṣe ọba orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), nítorí àwa kò ní ọba ní ilẹ̀ wa, àwọn ọba tí wọn ń fi ogun ja àwọn tí wọn ní  àwọn jọba lé lórí.

 A ò mọ ohun tí ẹ gbójúlé, tí ó ń mú inú yín dùn lórí àwọn ìwà ìkà tí ẹ ń hù sí àwa ọmọ Aládé, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa jẹ’wọ́ Ara Rẹ̀ fún yín láìpẹ́.