Lẹ́hìn tí àwọn amúnisìn ti ríi dájú pé, àwọn ti ṣẹ́gun àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni wọn wá ṣe àgbékalẹ̀ láti da orílẹ̀ èdè míràn papọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Yorùbá fún ìwúlò orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ti wọn. 

Lára àwọn àgbékalẹ̀ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà yìí dálé lóríí ìfipá jẹ gàba, ìmúnisìn, ìdókoòwò pẹ̀lú ẹ̀tàn. Látàrí ìwà ìkà yìí, kòsí ohun kankan tí arírimáṣe Nàìjíríà le dáṣe láìsí àṣẹ tàbí ìyọ̀nda àwọn amúnisìn alawọ̀ funfun yìí.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni, àwọn amúnisìn yìí wá lo èdè gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè wọn láti kó oríṣìríṣi orílẹ̀-èdè papọ̀ láti ṣe ìgbékalẹ̀ Nàìjíríà. Tíkò básí èdè gẹ̀ẹ́sì tójẹ́ èdè àwọn amúnisìn, oníkálukú kòní gbọ́ ara wọn yé n’ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.

Ńṣe ni àwọn amúnisìn náà ntẹ̀síwájú láti ma lo àwọn aṣojú wọn ni àpapọ̀ Nàìjíríà láti máa kó dúkìá, ọrọ̀, àlùmọ́nì inú ilẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá láti jẹ àǹfààní yìí ní orílẹ̀-èdè tiwọn, tí àwọn adàgbà má danú tí wọ́n pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ilẹ̀ Yorùbá, tí wọn lẹ́nu ṣùgbọ́n tí wọn kò lè fi sọ̀rọ̀ nítorí àgbékalẹ̀ àwọn amúnisìn lásán-làsàn ni ìlú aríremáṣe Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n Olódùmarè fẹ́ràn ìran Yorùbá, ìdí nìyí tó ṣe rán ìránṣẹ́ rẹ̀ Màmá wa, ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (MOA) láti jẹ́ olùdándè ìran Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú. Aṣe ìkéde òmìnira ilẹ̀ Yorùbá ní Ogúnjọ́ oṣù Belú ẹgbàá-ọdún-ólé-ní-méjìlélógún, èyí tí olórí Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ará Ìlú D.R.Y Bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọlá Ọmọkọrẹ tí  wọn ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún-ólé-mẹ́rin-lé-lógún ní orílẹ̀-èdè Olómìnira tiwantiwa ti Yorùbá.

Ọpẹ́ lóyẹ kí gbogbo ọmọ Yorùbà mà dú, fún òmìnira tòótọ́ ilẹ̀ Yorùbá.

Democratic Republic of the Yoruba