Tí a bá ns’ọ̀rọ̀ àwọn t’ó jẹ́ Àgbà’yà ní ilẹ̀ Yorùbá, l’oní, Bísí Àkàndé, tí ó ti f’ìgbà kan jẹ́ gómìnà ìpílẹ̀ Ọ̀ṣun rí, jẹ́ ìkan gbòógì, nínú wọn!
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XỌmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ló sọ eléyi, l’atàrí ọ̀rọ̀ kan tí akọ̀ròyín kan fi sí orí ẹ̀rọ ayélujá’ra.
Bísí Àkàndé jẹ́ ọmọ ọdún márun-dín-l’aádọ́run; ó ti pé ọmọ ọdún mẹ́wá kí wọ́n tó dá ilé-ẹ̀kọ́ Fásítì Ìbàdàn sílẹ̀; ilé-ẹ̀kọ́ náà fún’ra rẹ̀ sì ti pé ọdún márun-dín-l’ọgọ́rin tí wọ́n ti dáa sí’lẹ̀ báyi!
Àwọn bíi Bísí Àkàndé ti ní ọmọ; wọ́n ti ní ọmọ-ọmọ; wọ́n ti lẹ̀ tí ní ọmọ-ọmọ-ọmọ báyí!
Ṣé kò wá sí ọmọ irúfẹ́ wọn tàbí ẹni tí kò ti’lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀; tí ó le di irúfẹ́ ipò yẹn fún àwọn ìlú t’ó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá ni? – èyíinì, nàìjíríyà, k’á ti’lẹ̀ sọ wípé àwọn bàbá wọ̀nyí fẹ́’ràn nàìjíríà ju ìran wọn lọ!
Ká Ìròyìn: Àwọn Ìkà Èèyàn Fẹ́ Pààrọ̀ Ẹran Dáradára Pẹ̀lú Ẹran Ayédèrú
Kò sí èyí tí ó kàn wá pẹ̀lú nàìjíríà, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìyàl’ẹnu wípé àwọn bàbá wọ̀nyí, la ojú la’mú sí’lẹ̀ ní gbogbo ọdún tí ìyà ti njẹ ọmọ Yorùbá l’abẹ́ ìjẹgàba Fúlàní tí ó nṣe àkóso nàìjíríà, pàápàá nígbàtí a ṣì wà nínú nàìjíríà ní’gbà náà l’ọhun, kí ó tó di wípé a ti wá di orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ nísiìyí; tí àwọn bàbá òfò yí dẹ̀ wà nínú ìṣè’jọba nàìjíríà l’ati gbogbo ìgbà yẹn wá.
Ṣé a rántí wípé, Bísí Àkàndé yí ti jẹ́ Akọ̀wé Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní ọdún márun-dín-l’aádọ́ta s’ẹhìn; ó sì ti jẹ́ igbá-kéjì gómìnà Ọ̀yọ́ ní ọdún méjì-lé-l’ogójì s’ẹhìn; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti fi ṣe gómìnà Ọ̀ṣun ní ọdún mẹ́ẹ-d’ọgbọ̀n s’ẹhìn!
Ká Ìròyìn: Ààrẹ Senegal Mú Owó Ìrìnnà Kúrò Ní Àwọn Onjẹ Tí Ó Nwọlé Sí Ìlú Rẹ̀
L’oótọ́, a kò lè sọ wípé kí ẹnik’ẹni tí àwọn ìlú t’ó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá bá fi sí ipò kan tàbí òmíran, wípé kí irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ má gba ipò náà. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́bí ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, a wòó wípé, ṣé àwọn bàbá wọ̀nyí ò ri wípé ìyà ni àwọn fi njẹ ìran wọn, ní’gbà tí wọ́n bá nla’jú la’mú wọn sí’lẹ̀, tí oríṣiríṣi aburú ti nṣẹ’lẹ̀ sí ìran Yorùbá l’ati iye ọdún wọ̀nyí wá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé kìkìdá kí àwọn máa gba ipò l’abẹ́ naìjíríà, ni wọ́n mọ̀!
Tí a bá pè wọ́n ní àgbà’yà; òtítọ́ àti òdodo ni a sọ.