Irọ́ tí àwọn òyìnbó amúnisìn àgbáyé ń pa kìí ṣe kékeré rárá. Kìí ṣe nípa ìtàn àwa ọmọ Aládé tàbi ti gbogbo àdúláwọ̀ nìkan ni wọ́n ti pa irọ́.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe fún ìran Yorùbá, wọ́n ti sọ fún wa pé àwa ni a máa tún ìtàn òtítọ́ wa kọ, ìtàn ọmọ Yorùbá àti ilẹ̀ Yorùbá. Yàtọ̀ sí irọ́ lásán tí àwọn òyìnbó ń pa lórí ìtàn adúláwọ̀.
Láti ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti nfi àwòrán àlà-ilẹ̀ (map) àgbáyé hàn wá, èyí tí ó sì máa nfihàn pé ilẹ̀ àwọn òyìnbó (Europe àti Asia) tóbi ju ti Áfríkà lọ, ṣùgbọ́n irọ́ ni, wọ́n yàá bẹ́ẹ̀ lórí àwòrán inú-ìwé lásán ni.
Ẹ̀rí wà pé, tí a bá kó gbogbo ilẹ̀ Amẹ́ríkà, China, Indià, Japan, àti Mexico papọ̀, kò tíì tó ilẹ̀ Áfríkà. Èyí jẹ́ kàyéfì fún àwọn ènìyàn, nítorí pé wọ́n ti fi àwòrán map rú wa lójú pé Ilẹ̀ Europe àti ti Asia tóbi gidi ju ti Afríkà lọ, èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkànnì lórí ayélujára, ni àṣírí yí ti máa ntú síta, ṣùgbọ́n èyí tí a tún rí ni orí X, tí ó gbé fídíò kan jáde níbi tí òyìnbó kan tí nbéèrè pé kílódé tí wọ́n máa nfi ọwọ́ rọ́ Áfríkà sẹ́yìn?
Ọkùnrin ọ̀hún sọ pé lati apá ìwọ̀-oòrùn dé ìlà-oòrùn Russia, lórí àwòrán map, ó dàbí ìlọ́po méjì Áfríkà, ṣùgbọ́n irọ́ ni ó. Ó ní tí a bá rin ìrìn-àjò lórí ilẹ̀ gan-an gan, ìbú Áfríkà ju ti Russia lọ.
Ìbéèrè wá ni pé, kílódé tí wọ́n nṣe báyí? Láti mọ ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí, a kàn níláti rán ara wa létí àwọn nkan tí Màmá wa ti máa nsọ ni, Ìránṣẹ́-Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.
Wọ́n ní ìkóni-lẹ́rú-ọpọlọ (mental slavery) wà lára nkan tí òyìnbó-amúnisìn máa nlò láti fi da àwọn ènìyàn lórí rú.
Gbogbo wa ni a sì rántí ọ̀rọ̀ tí òyìnbó amúnisìn kan sọ pé, àwọn níláti jẹ́ kí aláwọ̀dúdú rí ohun ti òyìnbó bá ṣe bíi èyí tó dára ju ti aláwọ̀-dúdú lọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn kò ní le ṣẹ́gun aláwọ̀-dúdú.
Bí wọ́n ṣe purọ́ nípa ìtàn wa, ni wọ́n purọ́ nípa àṣà wa; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n purọ́ nípa ilẹ̀ àti àgbègbè aláwọ̀-dúdú, nínú ohun gbogbo, wọ́n ṣáà fẹ́ kí aláwọ̀-dúdú máa wo aláwọ̀-funfun gẹ́gẹ́bí “ọ̀gá,” tí èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Ṣùgbọ́n àwọn náà ti mọ̀ báyi pé pẹ̀lú dídìde tí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dìde yí, tiwọn ti bá wọn.
Ẹ jẹ́ kí á gbárùkù ti Ìjọba-Adélé wa lábẹ́ ìdarí Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, kí ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, lábẹ́ ìtọni àti Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ Màmá wa, MOA ó lè máa tẹ̀síwájú bí ó ti yẹ.
Kò b’ewu dé rárá: òmìnira Ìran Yorùbá ti dé: bí a ṣe máa ṣe àwárí Ìtàn òtítọ́ wa gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣe àwárí òtítọ́ ilẹ̀ wa, fún ìgbélékè Ìran Yorùbá títí ayé.